Ẹgbẹ́ tó ń ṣe ìjọba lọ́wọ́ ló ń lé iwájú nínú èsì ìdìbò tó ti ń jáde ní Angola

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Eto ìdibo Orilẹede Angola to lọ lọwọ tí ṣafihan ẹgbẹ oselu MPLA pe wọn borí lọwọ pẹlu esi ìdibo tí wọn ti fisita.

Ajọ to n risi eto ìdibo lorilẹede Angola ni awọn ka ida mẹrindiladọrun ninu ida ọgọrun un ìdibo naa, ti ẹgbẹ oselu Aarẹ João Lourenço to ti wa ni ìjọba fun ọpọlọpọ ọdun ni ida mejileladọta ninu ida ọgọrun un.

Tí awọn ẹgbẹ oselu alatako, Unita sìni ida mẹtalelogoji.

Awọn to risi ọrọ oselu ti ni awọn ẹgbẹ oselu naa igbagbọ pe awọn ẹgbẹ oselu mejeeji yoo ṣúmọ ra awọn pẹkipẹki.

Ìdibo naa ni gbagbọ wa pe yoo ni agbara lẹyin tí Orilẹede naa gba ominira lọdun 1975.

Ẹgbẹ oselu MPLA ni o ti ṣe ìjọba lati ogun ọdun sẹyin, ti o si le nira lati gba agbara lọwọ wọn.

Orilẹede Angola ni o dukia epo bentiro sugbọn ti isẹ ati arisẹse ṣe n da ọpọlọpọ awọn araalu lamu nitori awọn o ri anfani dukia naa.

Ẹgbẹ oselu mẹjọ lo kopa ninu eto ìdibo naa sugbọn ẹgbẹ oselu MPLA ati Unita ni igbagbọ wa yoo yan aarẹ tuntun.