Ẹ̀wù gbèsè ni APC gbé wọ Nàìjíríà láti 2015, bí mo ṣe fẹ́ ṣe ètò ààbò àti ọrọ̀ ajé bí mo bá di Ààrẹ nìyí - Atiku

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Olùdíje sípò Ààrẹ lábẹ́ àsíà òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar ti ní òun yóò gbé ìgbésẹ̀ akin láti kojú ìṣòro ètò ààbò tó ń bá orílẹ̀ èdè yìí fínra tí wọ́n dìbò yan òun. Atiku ní bí ó ṣe ku oṣù mẹ́fà kí ètò ìdìbò gbogbogboò ọdún 2023 wáyé, mímú àtúnṣe bá ètò ọrọ̀ Ajé tó ti dẹnu kọlẹ̀ ni òun yóò gbájúmọ́ ní kété tí òun bá wọlé gẹ́gẹ́ bí ààrẹ. Ní ìpínlẹ̀ Èkó, níbi ètò ọrọ̀ Ajé kan tó ṣe pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ àwọn tó ń rí sí ọrọ̀ Ajé (LCCI) ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni Atiku ti sọ ọ̀rọ̀ náà. “A máa ṣe àwọn ìpinnu tó lágbára láti wá ojútùú sí ìpèníjà tó ń ba ètò ààbò orílẹ̀ èdè yìí fínra.” Bákan náà ló bu ẹnu àtẹ́ lu bí ìṣẹ́ àti ebi ṣe ń da àwọn ènìyàn láàmú tó ní orílẹ̀ èdè yìí.

'Ọdun 2015 ni nnkan o ti lọ deede mọ fawọn araalu'

Atiku ní àìníṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wà lára ohun tí ètò ààbò fi ń mẹ́hẹ síi ní ojoojúmọ́ ní Nàìjíríà. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bí iná ètò ọrọ̀ Ajé Nàìjíríà ṣe ń jó àjórẹ̀yìn, ó ní láti ọdún 2015 ni ohun gbogbo kò ti lọ déédé mọ́ fún àwọn ènìyàn Nàìjíríà. “Ẹ̀ka epo rọ̀bì àti afẹ́fẹ́ gáàsì, tó jẹ́ okùn ẹ̀mí ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà ló ti rí ìfàsẹ́yìn mọ́kàndínlógún nínú ọgbọ̀n láti ọdún 2014.” “Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní Nàìjíríà ní ṣe ló dàbí wí pé Nàìjíríà ọrọ̀ ajé Nàìjíríà ti jó àjórẹ̀yìn pátápátá.” Atiku tẹ̀síwájú pé lábẹ́ ìṣèjọba tó wà lóde ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni kò níṣẹ́ lọ́wọ́ mọ́ bí ó ṣe lé ní mílíọ̀nù mẹ́tàlelógún ènìyàn tí kò níṣẹ́ lọ́wọ́ làsìkò yìí. Ó ní láàárín ọdún 2015 sí 2020, ìdá márùnléláàdọ́ta ni iṣẹ́ ti bọ́ lọ́wọ́ wọn láti mílíọ̀nù méjìdínláàdọ́rin sí mọ́kànlélọ́gbọ̀n.

'Ẹwu gbese ni Naijiria wọ!'

Atiku gbagbọ pé iye awọn ti ko ri isẹ pọ ju iye awọn to wa ni Ìpínlẹ̀ Eko lọ tabi awọn to n gbe ni olu ilu Abuja, Abia, Bayelsa, Cross River, Ebonyi, Kwara ati Ìpínlẹ̀ Nasarawa lapapọ. O fi kun un pe ọpọlọpọ awọn ti ko riṣẹ lo jẹ ọdọ ati obinrin to jẹ pe kii ṣe ọna ati ye nikan ni wọn n wa, sugbọn ti ko tun ni ireti ọjọ ọ̀la. Fun igba àkọ́kọ́ gẹgẹ bi Atiku ṣe sọ, ijọba Naijiria san owo gbese ju owo ti wọn pa wọle lọ leyi to ni wọn ti n kọja àlà owo ti ko yẹ ki wọn ti ọwọ bọ nípa nina ida to le ni ọgọ́rùn-ún owo to n wọle lori gbèsè. Loju tirẹ, Naijiria ti padanu ipò rẹ gẹgẹ bi ibudo ọrọ aje Áfíríkà to si ti di olori awọn ilu ti ko ni abusi Edumare mọ to sì da ẹbi rẹ ru ijọba to wa lode. "Ọpọlọpọ àwọn to wa ninu ìṣẹ́ loni pọ ju ọdun 2015 lọ, Atiku tẹnu mọ ọ pé koda nkan elo gan ti wọn kọja ohun táwọn araalu le ri owo ra lọ fún àpẹẹrẹ, búrẹ́dì to ti wọn kọja ida ọgọrun iye to jẹ lọdun 2020. "Awọn àgbẹ̀ n san ju ìdá igba bayii fun ajilẹ - ìyẹn bi wọn ba tilẹ̀ rii. Ijọba APC n wọ Naijiria lẹwu gbèsè! Naijiria ti re oko ìṣẹ́. Gbèsè ni Naijiria fi ń gbera látìgbà tí ìjọba APC ti wa lori oye lati ọdun 2015. Ọpọlọpọ awọn gbèsè yii lo si ti kọja ida mẹta iye gbedeke ti òfin gba laye."