Ní Ilorin, Àwọn ọmọ Yahoo rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá he, wo ẹ̀ṣẹ̀ tí òfin ká mọ́ wọn lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, others
Adajọ Muhammed Sani ti ile-ẹjọ giga to joko ni ilu Ilorin, nipinlẹ Kwara ti dajọ ki wọn fi Samuel Onojah ati awọn meji miran si ẹwọn fun ogun ọdun fun ẹsun lilu jibiti lori ẹro ayelujara.
Idajọ naa lo waye ni ọjọ Aiku, ọjọ Kejila Oṣu Kẹsan, ọdun yii.
Onojah to jẹ olorin ni adajo Muhammed ran ni ẹwon pelu pẹlu Victor Kadiyamo ati Jejelowo Segun, lẹhin ti wọn jẹwọ pe awọn jẹbi awọn ẹsun lilu jibiti lori ẹro ayelujara.
Ile iṣẹ ijọba to nisẹ pẹlu iwa jibiti EFCC agbegbe Ilorin lo gbẹ awọn meteta lo si ile ẹjọ.
Awọn ẹsun ti wọn fi kan Onojah ni gbigba Owó Pọ́ùn mẹ́jọ lọwọ Erica lọna aito eyi to lodi si abala 22 (2) (ii) eyi to de lilu jibiti lori ẹro ayelujara ninu ofin ọdun 2015, ati ijiya labẹ Abala 22 (2) (b) (iv) ninu iwe ofin yii kan naa.
Nigbati o n gbe Idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Muhammed dajọ ẹwọn ọdun mẹta fun Onojah lori ẹsun mẹta ti wọn fi kan an ati sisan owo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira fun ẹsun kọokan ninu ẹsun mẹta ti wọn fi kan.
Bakan naa ni wọn dajo ewon ọdun mẹta fun Kadiyamo lori ẹsun mẹta ti wọn fi kan an ati sisan owo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira fun ẹsun kini ati ikeji nigbati wọn ni ko san miliọnu mẹrin le ni aadọta.
Ni ti Segun, o ri idajọ ewon ọdun marun-un he tabi ko san owo itanran ẹgbẹrun lọna aadọta naira (500,000).














