Ṣé lóòtọ́ ni àwọn oníìbárà Opay àti Palmpay yóò pàdánù owó wọn léyìn àtẹ̀jáde NIBSS?

Oríṣun àwòrán, Opay /Palpay
Ileeṣẹ Opay ati Palmpay ti sọrọ soke lẹyin atẹjade ajọ Nigeria Inter-bank Settlement System, NIBSS, to ni ki awọn ile ifowopamọ yọ awọn ikanni ti awọn eeyan fi n san owo lori ayelujara kuro lara awọn banki ti wọn le maa fowo ranṣe si.
Lẹyin iroyin naa ni ọpọ ọmọ Naijiria, paapaa awọn to n lo Opay, Palmpay, Paystack, ati bẹẹbẹẹ lọ bẹrẹ si n kọminu lori ohun ti yoo ṣẹlẹ si owo wọn.
Amọ ṣa, lara awọn ileeṣe ti ọrọ naa kan ti kan si awọn onibara wọn latari ikede ọhun pe ko si ewu kankan fun wọn.
Ki ni Palmpay sọ?
Loju opo X rẹ ni Palmpay ti sọ fun awọn onibara rẹ pe “Ọrọ ti ajọ NIBBS sọ ko ṣe ipalara kankan fun Palpay nitori a gba ontẹ banki apapọ Naijiria, CBN, abo ajọ Nigeria Deposit Insurance Corporation, NDIC, si wa lori wa.
“Ẹ jọwọ, a maṣe naani iroyin ofege kọkan, a wa ni sẹpẹ lati ri daju pe nnkankan ko ṣẹlẹ si owo yin.”
Lẹyin naa lo kede nọmba ibarasẹnisọrọ ti wọn le pe fun iranlọwọ.

Oríṣun àwòrán, @palmpay_ng
Ẹ lọ fọkan balẹ - Opay
Ileeṣẹ Opay ti sọ fun awọn onibara rẹ ki wọn lọ fi ọkan wọn balẹ nitori mimi kan ko ni mi owo wọn to wa ni akata oun.
Opay sọ pe “A fẹ jẹ ko ye awọn eeyan pe atẹjade ajọ NIBSS ko kan ileeṣẹ Opay.”

Oríṣun àwòrán, Opay
“Ohun ti wọn n sọ wa fun awọn ileeṣẹ kan ti awọn eeyan n lo lati fi san owo lori ayelujara ‘Payment Service Solution Providers, Switches and Super Agents.”
O pari ọrọ rẹ pe banki alagbeka ni Opay jẹ, ati pe ko si nnkankan ti yoo ṣẹlẹ si owo awọn araalu to wa ni ikawọ oun.
Ki ni NIBSS sọ ni pato?

Oríṣun àwòrán, NIBSS
Ninu atẹjade ajọ naa kan to ni nọmba NIBSS/BD/NUP0/005/051723 lo ti sọ pe o lodi si ofin CBN ki awọn banki ni Naijiria fi awọn ikanni ti awọn eeyan kii n kowo pamọ si gba owo jade.
O ni awọn banki ori ayelujara naa le fi owo ranṣẹ si awọn araalu amọ wọn ko le maa gba owo wọle nitori aṣẹ ti CBN fun wọn ko gba wọn laaye lati ko owo araalu pamọ si apo wọn.
Lẹyin naa lo ni ki awọn banki yọ awon ileeṣẹ ti awọn eyan fi n san owo lori ayelujara naa kuro ni ara awọn ile ifowopamọ ti wọn le maa fowo ranṣẹ si kuro ninu ẹrọ wọn.














