NJC gba iṣẹ́ lọ́wọ́ adájọ́ ìpínlẹ̀ Osun, kọ ẹ̀bẹ̀ Adeleke láti yọ adájọ́ àgbà Adepele Ojo nípò

Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/AdabanijaQomaru

Ajọ to n ri si ọrọ awọn dajọ ni Naijiria, NJC, ti ni ki adajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Ssun, S.O. Falola lọ fẹyinti.

Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ti wọn ni o jẹbi ẹsun aṣẹ “Garnishee Order Absolute” rẹ lodi si ile ifowopamọ Polaris lori owo kan ti iye rẹ to ₦283,174,000.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ NJC, Adesoji Oye, fi lede, o ni iwadii awọn fi han pe adajọ naa tẹkọ leti lọ siluu Eko lati lọ ba agbẹjọro banki naa jiroro lori igbẹjọ to rọ mọ ọrọ owo ọhun, eyii ti ko yẹ ko ri bẹẹ.

Oye sọ ninu atẹjde rẹ pe “Ajọ National Judicial Council labẹ alaga adajọ Olukayode Ariwoola, GCON, ninu ipade rẹ ẹlẹkẹwaa to waye lọjọ kẹfa ati ọjọ keje, oṣu Kejila, ọdun 2023 ti fenuko pe ki adajọ S. O. Falola ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun lọ fẹyinti.

“Igbesẹ yii lo waye lẹyin iwadii igbimọ kan lẹyin iwe ti ọgbẹni Dapo Kolapo Olowo kọ lodi si i....”

Soji ni ajọ na ti kọwe si gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, ko buwọlu iyọnipo adajọ naa lẹsẹkẹsẹ.

Adepele Ojo ṣi ni adajọ agba ipinlẹ Osun – NJC

Ẹwẹ, ajọ NJC tun kọ ẹbẹ gomina Ademola Adeleke ipinlẹ Osun lati yọ adajọ agba, Adepele Ojo nipo.

Ajọ ọhun ni oun ko ni ṣisẹ pẹlu ohun ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Osun n fẹ.

O ni “Ajọ yii ti ṣagbeyẹwo, o ti si kọ ẹbẹ gomina Ademola Adeleke ti ipinlẹ Osun lati burawọle fun adajọ ti ipo rẹ ga julọ gẹgẹ bii adajọ agba fidihẹ lẹyin ẹsun ti wọn fi kan adajọ Adelepele Ojo, adajọ agba ipinlẹ Osun lẹyin ti ile igbimọ aṣofin ni ki wọn yọ ọ bii jiga.

“Ajọ yii fẹ fidi rẹ mulẹ pe adajọ ojo ṣi ni adajọ agba ipinlẹ Osun, a ko si ni ṣiṣẹ ni ibamu pẹlu ohun til ile igbimọ aṣofin sọ.”