'A máa wọ ìjọba àpapọ̀ lọ ilé ẹjọ́ lórí àdó olóró tí iléeṣẹ́ ológun jù sáwọn aráàlú ní Kaduna'

Aworan awọn to farapa ninu ikọlu naa

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Awọn ẹgbẹ Agbẹjọro lati apa Ariwa orilẹede Naijiria ti n leri lati wọ ìjọba apapọ orilẹede Naijiria lọ si ile ẹjọ, lati bere eto fun awọn eeyan to padanu ẹmi wọn lasiko ibu gbamu to waye ni agbegbe Tudun Biri.

O le ni ọgọrun eeyan to padanu ẹmi wọn lasiko ibu gbamu naa.

Nigba to n sọrọ ní orúkọ ẹgbẹ, Nafiu Abubakar salaye pe ẹgbẹ naa yoo ri pe awọn mọlẹbi to lugbadi iṣẹlẹ naa rí idajọ ododo gba.

Nafiu lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Kaduna rọ ìjọba apapọ lati gbe igbesẹ ni kiakia lati bẹrẹ iwadi lori iṣẹlẹ ibugbamu naa.

"O se koko pe ki awọn to lọwọ ninu ikọlu naa foju wina ofin lojuna ati dena irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ lọjọ iwaju.

"A rọ ileeṣẹ ologun lati se atunse eyi ti yoo mu adikun ba bi wọn ṣekupa awọn araalu.

Bakan naa ni ẹgbẹ ba awọn araalu kẹdun lori bi wọn ṣe padanu awọn eeyan wọn.

"A duro ti awọn eeyan yii lasiko ti nnkan le fun wọn yii, ti a yoo si pe fun idajọ ododo lori rẹ.

"A yoo se iṣẹ karakara ni ilana ofin lati ri pe a gba ẹtọ awọn eeyan yii fun wọn."

Ìjọba Nàìjíríà ń dọ́gbọ́n láti da ọwọ́ bo ìwadìí ikọlù àdó olóró t’ólógun jù s’áráàlú ní Kaduna

Diẹ lara awọn to ye ikọlu naa

Awọn ajọ ẹtọ ọmọniyan lagbaye ti n na ika si awọn alaṣẹ lorilẹede Naijiria lati rii pe wọn ṣe iwadi ikọlu ado oloro ti ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ ju si ileto Tundun Biri ni ipinlẹ Kaduna, lẹkun ariwa orilẹede Naijiria lai fi igba kan bọkan ninu rara.

Ninu atẹjade ọtọọtọ ti wọn fi sita, ajọ ajafẹtọ Amnesty International (AI) ati Human Rights Watch n fẹ ki ijọba Naijiria ṣeto idajọ ododo fun iranti awọn eeyan to ku ninu ikọlu naa atawọn ẹbi ti wọn fi silẹ.

Wọn ni o dara ki ijọba pese awọn eto to yẹ fun wọn lati bori ijakulẹ wọn.

Ọpọ ẹhonu lo ti jade si bi baalu Díronu ijagun ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ ni Naijiria ṣe ju ado oloro si aarin awọn eeyan ileto naa lasiko ti wọn fi n ṣe ajọyọ Maulud Nabiyy lopin ọsẹ to kọja.

Bi o tilẹ jẹ pe eeyan marundinlaadọrun ni ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri atawọn ajalu miran ni ipinlẹ Kaduna, SEMA kede pe o ba iṣẹ naa rin, amọ ọpọ eeyan lo n sọ pe iye awọn to ku ju bẹẹ lọ.

Aworan agbegbe ti ikọlu naa ti waye

A ko ri ababọ ọpọ ìwadii lori awọn to waye tẹlẹ -Amnesty International

Ọkan lara awọn saree ti wọn sin awọn to ku si

Oríṣun àwòrán, amnesty international

Nitirẹ, Ajọ Amnesty International, (AI) ti fi ẹsun kan ijọba apapọ Naijiria pe o n gbiyanju lati fi ere rabata bo iwadii ikọlu ado oloro ti ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ ju si ileto Tundun Biri ni ipinlẹ Kaduna, lẹkun ariwa orilẹede Naijiria.

Ẹka ajọ Amnesty International lorilẹede Naijiria ni iwadii awọn ti fihan pe aadọrin eeyan ni wọn sin si ọkan lara saare ọlọpọ ero meji ti wọn gbẹ fi sin awọn eeyan ti ado oloro naa pa.

Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu BBC, oludari ẹka ajọ Amnesty International lorilẹede Naijiria, Malam Isah Sanusi ṣalaye pe kii ṣe igba akọkọ ree ti irufẹ ikọlu bẹẹ yoo maa waye.

O ni bi ijọba ti ṣe ṣeleri iwadii to lori awọn irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ to ti waye sẹyin, ko si eyi ti araalu ri abajade iwadi wọn.

Ajọ Amnesty International ni iwadii to loorin gbọdọ waye lori iṣẹlẹ yii nitori pe eyi gan an lo le ran awọn awọn ologun funrawọn gan lọwọ nitori pe “inu awọn naa pẹlu ko dun si ohun to ṣẹlẹ naa.

Human Rights Watch ni ijọba gbọdọ gbe igbimọ ti kii ṣe tijọba kalẹ fun iwadi

Lara awọn ti o faragba ikọlu naa

Anietie Ewang to jẹ oluwadi ijinlẹ fun ajọ Human Rights Watch lorilẹede Naijiria ni tirẹ kọminu lori bi awọn alaṣẹ ‘ko tii ṣe gbe igbesẹ to yanranti latiṣe ohun to tọ” lori awọn irufẹ iṣẹlẹ yii to ti waye sẹyin.

“O yẹ ki awọn adari ileeṣẹ ologun fimufinlẹ gidigidi lati dena atunṣẹ irufẹ iṣẹlẹ to n gbẹmi ọpọ yii ati eto arẹmọlẹkun fun awọn to fara kaasa rẹ. Ki wọn bẹrẹ pẹlu igbimọ iwadi ti ko ni fi si iha kankan.”