Èèyàn 4.8 mílíọ̀nù ni ebi ń pa, iléẹ̀kọ́ 9000 di títìpa nítorí ọ̀rọ̀ àbò tó mẹ́hẹ - Ecowas

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn adari lẹkun iwọ-oorun Africa (Ecowas) ti kilọ pe eto abo lo tubọ n dẹnukọlẹ sii lorilẹede Burkina Faso, Mali ati Niger.
Aarẹ igbimọ Ecowas, Ọmọwe Omar Alieu Touray, to ṣe ikilọ yii ni Ọjọru nibi ipade igbimọ ajọ naa to n moju to ilaja ati eto abo nilu Abuja, wi pe iditẹ gbajọba ati ayipada ijọba lọna ti ko ba ofin mu lo n mu ki eto abo o mẹhẹ lẹkun naa.
Touray wi pe ẹtalelẹẹdẹgbẹjọ ni akọlu awọn agbesunmọmi to ti waye ni Burkina Faso lati ọjọ kini oṣu kini si ọjọ kejilelogun oṣu kẹwa ọdun yii.
Bakan naa ni ẹrinlelogojilelẹgbẹrun irufẹ akọlu bẹẹ ti waye ni Mali, ti orilẹede Niger si ti ẹrindinlọgọrinlelọọdunrun irufẹ akọlu yii lati igba ti iditẹgbajọba ti waye nibẹ loṣu keje ọdun yii.
Touray wi pe “ipa ti aisi abo to peye yii n ni lori awọn eniyan lo lagbara ni eeyan miliọnu mẹrin ati ẹsun mẹjo ṣe n kojuiṣoro airi ounjẹ jẹ ni Burkina Faso, Mali ati Niger, ti miliọnu meji ati ẹsun mẹrin si di atipo laarin ilu wọn, to fi mọ ileẹkọ bii ẹgbẹrun mẹsan ti wọn ti ti pa”.
Aarẹ igbimọ Ecowas ọun to woye ipenija ti iṣelu, eto abo, ati ijọmọniyan n doju kọ lawọn orilẹede kan lẹkun naa wi pe “ẹkun yii n koju oniruuru ipenija eto abo ati iṣejọba, to fi mọ igbesunmọmi, idojukọ awọn agbebọn, gbigba ijọba awaarawa pada lọna aitọ, ati idjukọ ijọmọniyan gidi”.
Ipade igbimọ ajọ naa to n moju to ilaja ati eto abo lo n waye ṣaaju ipade awọn minisita ajọ naa ti yoo waye loni Ọjọbọ lati jiroro lori alaafia, eto abo ati idagbasoke ẹkun naa.
Eyi lo n waye bi orlẹede Mali, Niger ati Burkina Faso ṣe n gbe igbesẹ lati da ẹgbẹ mii kalẹ ti wọn pe ni ‘Alliance of the Sahel States’ ti yoo gbena woju bi ajọ Ecowas ṣe n jẹ gaba lori oṣelu ẹkun naa.














