Èèyàn 2.6 mílíọ́nù ló ń kú lọ́dọdún nítorí ọtí àti ẹlẹ́rìndòdò mímu – WHO

Oríṣun àwòrán, Pexels/ Pixabay
Ajọ WHO ti ke si awọn ijọba kaakiri agbaye ki wọn fi kun owo ori ti wọn n gba lori awọn ọti ati ẹlẹrindodo.
WHO ni eyii yoo mu adinku ba iye eeyan to n ku latari pe wọn n mu awọn ọti naa, eyii to n ṣakoba fun ilera wọn.
Ọjọ Iṣẹgun ni WHO fi atẹjade kan lede, ninu eyii to ti tu pẹrẹpẹrẹ awọn ohun ti awọn araalu n mu ti ko ṣe agọ ra wọn lanfani.
Gẹgẹ bii ohun ti WHO sọ, o le ni miliọnu meji abọ eeyan to n ku larari ọti mimu kaakiri agbaye, nigba ti miliọnu mẹjọ eeyan mii n papoda latari oun ti wọn n jẹ, eyii to n ṣakoba fun agọ ara wọn.
O ni ti ijọba ba fi owo ori gọbọi le awọn ohun mimu naa, yoo jẹ ki awọn ileeṣẹ to n po awọn ọti ọhun maa po awọn to le ṣe ara eeyan loore.
Iwadii kan lọdun 2017 fi han pe ti ijọba ba fi afikun 50% si owo ori ọti, yoo gba ẹmi miliọnu mọkanlelogun eeyan to yẹ ko ku la, yoo si fun ijọba ni owo ti iye rẹ to tiriliọnu mẹtadinlogun.
Ti iye ọti ba din ku, iye iku araalu yoo din ku
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
WHO sọ pe gbigbe owo le owo ori ẹlẹrindodo yoo din awọn aisan kan ku.
Lara awọn aisan naa ni aisan ọkan, aisan rọpa-rọsẹ, itọ ṣuga, jẹjẹrẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O ni ti wọn ba gbe owo le owo ori awọn owo ọti naa, yoo din iye eeyan to n mu awọn ọti ọhun ku, yoo si mu adinku ba ijamba oju popo ati bi awọn eeyan ṣe n ṣẹ si ofin irinna oju popo.
Iye kalori meloo lo wa ninu ọti ẹlẹrindodo kan?
Iwadii kan ti awọn onimọ eto ilera ṣe nilẹ Amẹrika fi han pe awọn eeyan Amnẹrika maa n mu kalori 157 loojọ ninu awọn nnn kan ẹlẹrindodo ti wọn n mu.
Gẹgẹ bii atẹjade ileeṣẹ to n ṣe Coca-Cola, igo Coca-Cola to jẹ iwọn 330ml lo maa n ni ṣuga ti iwọn rẹ jẹ 35g, eyii to n tumọ si ṣibi ṣuga meje ninu igo naa.
WHO ni eeyan ko gbọdọ maa jẹ ju aadọta giramu ṣuga lọ loojọ.
Lorilẹ-ede Chile, nnkan bii 18 kalori ni wọn mu loojọ lẹnikọọkan wọn, amọ o ti bẹrẹ si n gbe owo ori nla le ṣuga lori.
Yatọ si orilẹ-ede yii, awọn orilẹ-ede mii bii ọgbọn lagbaye lo ti gbe owo ori nla le ṣuga lori.












