Mí ò ní kọrin kẹ̀? Ìdí réè tí Portable fí ní dandan ní kí òun kọrin ní ṣọ́ọ̀ṣì Celestial tó pè é sí àṣalẹ́ ìyìn

Oríṣun àwòrán, @portablebaeby
O tun ti n mura lati zeh!
Gbajumọ olorin takasufe Naijiria nii, Habib Okikiola, ti ọpọ mọ si Portable Ọmọ Ọlalọmi ti fesi lori ikede ile ijọsin Sele kan to ni awọn ko fẹ ko wa kọrin mọ nibi aṣalẹ iyin ti wọn ṣeto.
Ile ijọsin yi to w ni ipinlẹ Eko ti orukọ rẹ n jẹ Land Of Goshen Cathedral lo palu ẹnu da latari bi awuyewuye ṣe tẹle ikede pe Portable ati Wasiu Alabi Pauma yoo wa kọrin nile ijọsin naa.
Ninu fọnran fidio kan to fi sita, Olalomi Portable sọ pe oun ti gba miliọnu Naira lọwọ ile ijọsin naa tori naa o di dandan ki oun wa kọrin fun wọn.
O ni ''Ile ijọsin Cele, a gbọdo wa kọrin ni o.Ẹ ti san miliọnu marun un Naira fun mi.Pasuma yoo kọrin.Emi naa yoo wa kọrin.''
Olori ijọ Cele Olatosho Oshoffa lo kede loju opo rẹ ni Facebook pe ijọ Cele lapapọ ti wọgile ki Pasuma ati Portable wa kọrin lalẹ iyin ijọ naa.
O fikun pe ''awa ọmọ Ọlọrun n bọ,ijọ Land of Goshen mo bẹ yin lorukọ Ọlọrun, ẹ wo ti awa ọmọ Ọlọrun,ẹ ma wo irinisi wa''
Ibi ọrọ ti n rugbo bọ
Latigba ti iwe ipe to n kede Aṣalẹ Ankara ati Iyin lati ẹka Ṣọọṣi Sẹlẹ kan ti jade, nibi ti wọn ti pe olorin Fuji, Alabi Pasuma ati gbajumọ olorin takasufee, Habib Okikiola ti ọpọ mọ si Portable Ọmọ Ọlalọmi lati waa kọrin lawọn eeyan ti n sọ oriṣiiriṣii ọrọ nipa ṣọọṣi naa.
Ọjọru, ọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu Kọkanla ọdun 2023 ni iwe ipe to n kede Aṣalẹ iyin naa jade sori opo ayelujara Facebook.
Ẹka ijọ Mimọ to pe Pasuma ati Portable naa ni wọn pe orukọ rẹ ni Land Of Goshen Cathedral.
Yatọ si Pasuma ati Portable ti wọn jẹ olorin aye, awọn eleto naa tun pe ọmọbinrin olorin kan torukọ rẹ n jẹ May-Shua.
Ẹfanjẹliisi Sunday JP, tawọn eeyan tun mọ si De Governor, (Eebudọla 1 of Lagos) ni pasitọ to han ninu iwe ipe ọhun.
Olori ijọ tapa si pipe Portable lati wa kọrin

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Olori ijọ Sele lapapọ Olatosho Oshoffa ni nkan bi ọsẹ kan sẹyin lo kede pe Portable ko ni kopa nibi isin aṣalẹ tawọn fẹ ṣe.
O ni oun ti ba ẹfanjẹlisti ijọ to fi ikede yi sita sọrọ ti o si ti gbọ agbọye pe awọn ko faaye gba olorin aye lati wa sibi eto isin ijọ naa.
Ikede yi ni o mu ki Portable fesi pe ki wọn jọwọ jẹ kioun ati Alhaji Pasuma ti wọn fiwe pe tẹlẹ lati wa kọrin nibi aṣalẹ iyin ijọ naa.
A ko ti gbọ esi kankan lati ọdọ Wasiu Alai Pasuma lori ikede ti olori ijọ naa fi sita ṣaaju tabi ọrọ ti Portable sọ laipẹ yi.
Bo tilẹ jẹ wi pe o ṣeeṣe ki Portable maa fi ọrọ yi dapara a ko ti mọ boya ile ijọsin naa yoo yi ọkan pada lati faaye gba olorin yi to ni ''Ọmọ Ọlọrun loun n ṣe''
Kini ibaṣepọ awọn olorin aye pẹlu ile ijọsin ni Naijiria?

Oríṣun àwòrán, Olatosho Oshoffa
Ẹsin jẹ opo kan pataki fun awọn ọpọ eeyan lorileede Naijiria.
Yala wọn jẹ musulumi Kristẹni tabi oniṣẹṣe ọpọ lo maa n wa oju re ẹlẹda nipasẹ jijọsin.
Ijọsin yi lọpọ igba a si maa lọ nipasẹ orin kikọ ati ijo ni paapa niu ẹsin Kristẹni ati ti abalaye.
Ninu Islam, itako wa lọdọ awọn kan si orin kikọ ti wọn si tun ni alakalẹ lori iru orin ti eeyan le kọ ati boya o ba ẹsin mu.
Pupọ awọn ijọ Kristẹni lo maa n la aaye kalẹ fun ijo ati orin ti wọn si ni awọn ọm ijọ to jẹ akọrin to maa n kọ orin ẹmi lasiko ijọsin.
Ọlaju ati iyipada ni awọn ile ijọsin kan ti mu ki awọn olorin ti kii ṣe olorin ẹmi kọọkan maa gba ipe lati ọdọ ijọ ki wọn wa fi orin ra ẹmi ni paapa awọn ọdọ to nifẹ si iru olorin bẹẹ.
Lootọ kii ṣe gbogbo ijọ lo faaye gba iru nkan bayii ṣugbọn awọn mi ko bikita lati faaye gba awọn akọrin aye tabi adẹrinpoṣonu lati wa da awọn ọmọ ijọ laraya.
Lagbo awọn olorin naa, ko jẹ tuntun mọ lati ri ajọṣepọ orin kikọ laarin awọn olorin ti wọn pe ara wọn lolorin ẹmi musulumi ati Kristẹni ti wọn jijọ n kọrin papọ.
Loju awọn eeyan kan iru nkan bayi ko bojumu.
Iru awọn bẹẹ lariwo wọn si po to ṣeeṣe ko jẹ pe ijọ Sele gbọ ti wọn si fi ni ki Pasuma ati Portable ma ṣe kopa lalẹ isin wọn.
Orin ati ijo jẹ origun pataki ninu ijọsin awọn Sele lorileede Naijiria.














