Nàìjíríà fẹ́ ta bàlúù ààrẹ

Oríṣun àwòrán, @NigAirForce/X
Ileeṣẹ ologun ofurufu lorilẹede Naijiria lo ti gbe ọkna lara awọn baluu aare ilẹ naa, Falcon 900B, sori igba ti wọn si wi pe kawọn araalu to ba nifẹ sii o fiwe ṣọwọ si wọn lati duna-dura.
Ninu atẹjade kan loju opo X ajọ naa, wọn wi “ijọba apapọ orilẹede Naijiria lo fọwọ si tita baaluu Falcon 900B to jẹ to ajọ ologun ilẹ yii”.
Ajọ naa wi pe gbogbo eniyan to ba nifẹ si rira baaluu naa ni awọn pe ko fiwe ṣọwọ si wọn ni ibamu pẹlu ofin tita ati rira ẹru fun ileeṣẹ ati ijọba ti ọdun 2007.
Ileeṣẹ ologun ọhun wi pe “awọn to ba fẹẹ fi ṣe atẹjiṣẹ ori ẹrọ ayelujara gbọdọ fi kọkọrọ idaabobo si ki wọn si fi ranṣẹ si [email protected] ati kọkọrọ idaabobo naa si proc2@ airforce.miI.ng.
“Ẹni to ba fẹẹ mu iwe idunadura rẹ wa funra rẹ ni ko ki finu apoowe pelebe ti yoo lẹ pa, ko si kọ orukọ ati adirẹsi rẹ abi ti ileeṣẹ rẹ sii lara, to fi mọ ijuwe ohun to fẹẹ ra.
“Bakan naa ni ki wọn kọọ sii lara pe ‘ẸNIKÉNI KO GBỌDỌ ṢII ṢAAJU ỌJO KẸRINLELOGUN OṢU KEJILA ỌDUN 2024.”
Ajọ ologun naa waa fi kun pe ni kete ti ọjọ naa ba pe ni awọn yoo bẹrẹ ayẹwo gbogbo awọn iwe to ba wọle.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post








