Àwọn sẹ́nétọ̀ jọ̀wọ́ ₦109m owó oṣù wọn fáwọn tó bá ìkọlù àdó olóró tó wáyé ní Kaduna lọ

Ile aṣofin agba

Oríṣun àwòrán, @senatengr/X

Àwọn Sẹ́nétọ̀ ti ile aṣòfin àgbà Nàìjíríà ti ṣàgbékalẹ̀ owó oṣù wọn fún ti oṣù Kejìlá ọdún 2023 fún àwọn tó lùgbàdì ìṣẹ̀lẹ̀ àdó olóró tí iléeṣẹ́ ológun ṣèṣì jù sí Tudun Biri, ìjọba ìbílẹ̀ Igabi ní ìpínlẹ̀ Kaduna.

Àpapọ̀ owó oṣù àwọn Sẹ́nétọ̀ náà ni wọ́n ló jẹ́ mílíọ̀nù mọ́kàndínláàádọ́fà.

Igbákejì ààrẹ ilé aṣòfin àgbà, Sẹ́nétọ̀ Barau Jibrin ló fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ nígbà tó ṣaájú ikọ̀ kan lọ sí ilé ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna láti báwọn kẹ́dùn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, Sẹ́nétọ̀ Uba Sani ló gbà wọ́n ní alèjò.

Sẹ́nétọ̀ Barau, nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ rẹ̀, Ismail Mudashir fi léde, ní àwọn máa fi owó ọ̀hún sí akoto gómìnà Sani láti pin fún àwọn ènìyàn tí ìkọlù náà ṣe àkóbá fún.

Nígbà tó ń bá ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna àtàwọn ènìyàn Tudun Biri kẹ́dùn lórí ìkọlù náà, Barau ní ilé aṣòfin apapọ̀ yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú iléeṣẹ́ ààrẹ láti fìdí ohun tó ṣokùnfà àṣìṣe tí iléeṣẹ́ ológun ṣe náà.

Gómìnà Uba Sani nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn aṣòfin náà tẹmpẹlẹmọ́ ìdí tí wọ́n gbọ́dọ̀ fi kún ìjọba àpapọ̀ lọ́wọ́ láti ṣewádìí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.

Bákan náà ló rò wọ́n láti ṣàgbéyẹ̀wò ìpè fún ìdásílẹ̀ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ kí ètò ààbò Nàìjíríà le dúró ire si.

Ọ̀gá àgbà Iléeṣẹ́ ológun tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ àwọn èèyàn Tudun Biri

Aworan ọga ileeṣẹ ologun

Oríṣun àwòrán, Nigeria Army

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣaaju ni ọga agba ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria, Ọgagun Taoreed Lagbaja ti tọrọ aforijin lọwọ awọn eeyan agbegbe Tudun Biri nipinlẹ Kaduna fun isẹlẹ ibu gbamu to gba ẹmi ọpọlọpọ eeyan ti awọn mi si tun farapa yanayana.

Ninu atẹjade kan ti Ileeṣẹ ologun fi sori opo ayelujara wọn, Ọga ologun sabẹwo si agbegbe naa lati ba awọn ara agbegbe naa kẹdun lori isẹlẹ naa.

Ọgagun Lagbaja ni isẹlẹ naa waye lasiko ti ileeṣẹ ologun n se ọfintoto agbegbe ti wọn kẹfin awọn janduku, ti wọn si ṣeesi ju ado oloro si aarin awọn eeyan to n se ajọdun Maolud Nabiyy, ti wọn ro pe wọn jẹ janduku,

O fidi rẹ mulẹ pe iwadii ti bẹrẹ lati sawari ohun to sokunfa asise naa ati o ṣe koko lati se iwadi naa lati gbegi dena irufẹ isẹlẹ naa lọjọ iwaju.

Ọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lo ti fẹhonu wọn ran sita lori isẹlẹ ibu gbamu naa, ti Aarẹ Bola Tinubu si ti paṣẹ pe ki iwadi bẹrẹ ni kiakia.

Ajọ to n risi isẹlẹ pajawiri lorilẹede Naijiria, NEMA ni o ti to eeyan marundinlaadọruun to ti padanu ẹmi wọn lẹyin ibu gbamu naa, ti eeyan ọgọta si wa ni ile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju sugbọn awọn ajọ to n ja fẹtọ ọmọniyan gbagbọ iye eeyan to ku ju bẹ iyẹn lọ.

Èèyàn 85 ló pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìbú gbàmù Kaduna

Aworan Ileeṣẹ ologun

Oríṣun àwòrán, AFP

Ajọ to n risi isẹlẹ pajawiri nipinlẹ Kaduna ni o to eeyan marundinlaadọrun to padanu ẹmi wọn nibi isẹlẹ ibu gbamu ado oloro to waye nipinlẹ naa.

Ajọ naa ni eto isinku ti waye fun awọn eeyan naa ni agbegbe ilu Tudun Biriin nijọba ibilẹ Igabi nipinlẹ Kaduna, ti iwadii si ti bẹrẹ.

Saaju ni Ileeṣẹ ologun ofurufu Naijiria pariwo sita pe awọn ko mọ ohunkohun nipa bu gbamu naa.

Lanaa, Ọjọ Aje, ọjọ kẹrin oṣu kejila ọdun 2023, Ile igimọ aṣofin ile Naijiria palasẹ pe ki iwadii bẹrẹ lẹyin ti Ileeṣẹ ologun kede pe awọn ni wọn ju ado oloro naa si laarin awọn olujọsin nibi ayẹyẹ Maolud Nabiyy.

Aarẹ Tinubu ba awọn mọlẹbi kẹdun

Aarẹ Bola Tinubu ti ba awọn mọlẹbi awọn to padanu ẹmi nibiisẹlẹ ibu gbamu ado oloro to waye ni agbegbe Tudun Biriin nijọba ibilẹ Igabi nipinlẹ Kaduna.

Aare sapejuwe isẹlẹ naa gẹgẹ bi ohun to ba ni lọkan jẹ pupọ, to si tun gba oni je.

Aarẹ ninu atẹjade ti Oludamọran rẹ, Ajuri Ngelale buwọlu fun akọroyin ni oun ti paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ ni onikiakia, to rọ awọn araalu lati se suuru nitori awọn yoo ri pe otitọ farahan.

Bakan naa ni Aarẹ ni oun ti pasẹ ki itọju bẹrẹ fun awọn eeyan to farapa. To si tun gba ladura pe ki Ọlọrun forijin awọn to ti jade laye.