'Bàbá mi wọ aṣọ ọkùnrin fún mi fún ọdún mẹ́wàá láti dáàbò bò mí'

Oríṣun àwòrán, NILOFAR AYOUBI
Oju Nilofar Ayoubi si pọn lẹyin to jẹ igbaju lasiko to n sere loju ọna Kunduz ni apa ariwa Afghanistan.
Ko ti pe ọmọ ọdun mẹrin nigba ti ọkunrin kan to ni irungbọn wa siwaju rẹ, o fọwọkan ni aya rẹ lati tẹ ni ọyun. Lẹyin to fu ifọti, o wa sọ fun pe ti oun ba tun ri lai wọ Hijah, oun yo sọ fun Baba rẹ.
Nilofar ranti ohun to waye ni ọdun mẹtalelogun sẹyin, ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC, o ni “Mo lọ ile pẹlu omije, ti inu si bi Baba mi, ti oju rẹ si pọn.”
“Mo ranti pe o kan rin lọ rin bọ, to si kigbe pe “Ta lo bi e mi gan da lati fọwọ kan ẹ.”
Nibẹ lo ti pinnu, “O ni ki iya mi lọ abẹ wa, to di ge irun mi, sọ fun pe ko ma mura fun mi bi ọkunrin.”
Nilofar dagba ni Afghanistan lasiko ti Taliban kọkọ se ijọba ni ọdun 1996 si 2001.
Fun bi ọdun mẹwaa, iya mi n mura fun mi gẹgẹ bi ọkunrin lati bori awọn ilanna ti awọn ẹgbẹ yii gbe kalẹ fun obinrin.
Lonii, bi o ṣe n gbe ni orilẹede Poland, o n ronu igba ewe rẹ, bi o se dagba ni agbegbe to le lati gbe lagbaye, ibi ti iru ọmọ to ba jẹ ninu obinrin tabi ọkunrin ni yoo safihan awọn anfani to lẹtọ si.
Bi o se dagba

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọn bi Nilofar ni ọdun 1996, bitilẹ jẹ pe iwe irina rẹ ni ọdun 1993 ni wọn bi. Baba rẹ fẹ ko tete bẹrẹ ile ẹkọ lẹyin ti awọn ọmọ ogun Amẹrika le Taliban wọle ni ọdun 2001.
“Jijẹ ọkunrin yoo fun ẹ ni anfani , koda ko jẹ pe ọmọ ọdun meji ni ẹ, to ba ti jẹ ọkunrin, o tumọ si pe o ni aponle ju iya to bi ẹ lọ. To ba ti de ọmọ ọdun mẹrin, o le ma pasẹ fun iya rẹ, o da bi ẹru ati pe gẹgẹ bi obinrin, ko si ẹni to ri ẹ.”
Nilofar ni eyi lo fa ki ọpọ awọn mọlẹbi ma mura fun awọn ọmọ obinrin bi ti ọkunrin, paapa to ba jẹ pe idile naa ko ni ọkunrin to n pese fun wọn nitori ibẹru pe ọkunrin to ba ni owo le pada obinrin ti ko ni oluranlọwọ ko si fi se aya.
“Ni temi, o yatọ. Ko ki n sepe n ko ni oluranlọwọ ọkunrin ohun lo jẹ ki gbe aye to rọnu.”
Itusilẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi o se gbe nibẹ pẹlu irun ẹ to gẹ , to si n wọ aṣọ awọn ẹgbọn rẹ ọkunrin. Nilofar ko mọ bi igbe aye rẹ se yipada.
“Mo bẹrẹ sini ma jẹ awọn anfani ti awọn ẹgbọn mi ọkunrin n jẹ. Mo tẹle baba mi lọ si ọja pẹlu aṣọ ọkunrin. Mo le wọ ọkọ lọ wo ere idaraya. Mo bẹrẹ si ni ma ni ọrẹ ni agbegbe wa, ti mo si le jade igbakugba to ba wu mi lati lọ seere.”
Sugbọn awọn obinrin si n gbe bi awọn obinrin Afghann se n gbe ni ọpọ igba. Wọn ni lati bo ori wọn nigba ti wọn ba fẹ jade sita, aṣọ ti yo bo wọn lati ori wọn de ẹsẹ wọn, to si jẹ pe nnkan ti baba wọn fẹ niyẹn.
“Baba mi ko fẹran pe ki a ma wọ aṣọ ibilẹ nile. O ma ba iya wa ja pe kilode to fi mura fun wa bayii. Aṣọ naa gun . Ki lo de ti aṣọ naa gun bayii?
Sise ọkan akin
Nilofar ni bi oun se dagba pẹlu idanimọ meji mu oun da yatọ. Ẹnikan to mọ ohun to la kọja ni ọrẹ timọtimọ nigba to n dagba, to jẹ obinrin to n gbe bi ọkunrin bi tiẹ. Awọn mejeeji da bi korikosun ninu wahala to wa niwaju wọn.
Nilofar ranti pe “a da bi korikosun, ni gbogbo igba, ti wọn ba fẹ mu kan laarin wa, ẹnikeji yoo gba silẹ.”
O ni eyi jẹ ki ọkan rẹ le gẹgẹ bi ti ọkunrin, to si ni fun awọn eeyan lati damọ pe obinrin ni. Ni agbegbe rẹ, o n se bi awọn ọkunrin yooku, ti yoo buramọ awọn obinrin, pe wọn rẹwa.
Nitori anfani yii, ko kọ lati gbe igbe aye obinrin Afghan ni ilana asa, ti ko si sumọ awọn obinrin.
“N ko ki ba awọn obinrin rin. Ohun to waye pẹlu wọn ni ko ye mi rara. Nitori ri rẹ ni o n ko fi mọ nipa nnkan oṣu obinrin”
Nilofar ri ipolowo paadi obinrin lori ẹrọ momaworan sugbọn ko mọ ohun ti wọn ti wọn fi n se.
Lọjọ kan , mo ri paadi kan, mo saare lọ fun baba mi pe “Baba mi ẹ wo nnkan ti mori, o dabi nnkan ti mo ri lori ẹrọ momaworan, bawo ni wọn se lo? Baba mi wo mi, o ni pun ko mọ.
“Mo lọ bere lọwọ ẹgbọn mi obinrin. Mo ranti pe o sure gba lọwọ mi.”
Lati igba na, ẹnikẹni ko sọ fun nipa nnkan oṣu obinrin.
Pada si awọ obinrin

Oríṣun àwòrán, NILOFAR AYOUBI
Lẹyin ti Nilofar kopa ninu idije Judo ni ọmọ ọdun mẹtala, o bẹrẹ si ni ma ni awọn irora kan ni ẹsẹ rẹ, bi o se fẹ sun, o lọ ninu ile igbọnsẹ, to si ri ẹjẹ, ryi to dẹru ba pupọ ti ko si mọ pe eyi yoo tun yi igbesi aye rẹ pada.
“Lọjọ keji, mo sọ fun ọrẹ mi, o bẹrẹ si ni ma fi rẹrin , pe se awọn ẹgbọn mi ko sọ fun mi.” Ọrẹ rẹ ti wọn jọ n se bi ọkunrin lo fi nnkan ti wọn n fi paadi n se , eyi to ti lori ẹrọ momaworan.
“Mo lọ si ile, iya ri nnkan to jade lati ninu aṣọ mi, ti mo si reti pe ko pẹtu si mi lọkan sugbọn o bẹrẹ si ni ma sọ pe ki ni idi ti mo fi tete dagba.”
Iya rẹ bẹrẹ si ni ma sunkun nitori ojo ọla Nilofar yoo da bi tiẹ ati ti awọn ọmọ rẹ obinrin ti wọn ti mọle.
Lọdun 2021 ti Taliban gba ijọba, ti orilẹede Amẹrika ati awọn orilẹede si kuro Afghanistan nigba naa ni idile Nilofar mọ pe o yẹ ki awọn kuro.
Ni bayii, Nilofar ti wa ni ẹni ọdun mọkandinlogun, ti ero rẹ si ni ọkọ to ba fẹ yoo dipo ti Baba to ku ko to se igbeyawo.
“Ko le dabi baba mi sugbọn o igbiyanju.”
Lẹyin gbogbo lasigbo naa, Nilofar ati mọlẹbi rẹ kuro, ti wọn si lọ orilẹede Poland nibi ti igbeaye wọn ti yipada.















