Ṣé lóòtọ́ ni pé àìsàn ìtọ̀ ṣúgà ‘Diabetes’ ló pa Adebayo, ọmọ Alaafin Oyo? Gómìnà Makinde sọ̀rọ̀ nípa ìlera rẹ̀

Aworan Alaafin Adeyẹmi kẹta, Ọmọọba Adebayọ Adeyẹmi ati Gomina Ṣeyi Makinde

Oríṣun àwòrán, others/x/Seyi makinde

Ni ọjọ Ẹti Ọjọ kẹjọ oṣu kejila ọdun 2023 ni iroyin iku ọkan lara awọn ọmọ ọkunrin ti Alaafin Ọyọ to waja , Ọba Lamidi Adeyẹmi kẹta fi silẹ, Adebayọ Adeyẹmi jade laye.

Ile iwosan nla UCH ni ilu Ibadan ni Adebayọ ti ọpọ mọ si ‘De Gov’ dakẹ si ni idaji ọjọ Ẹti.

Amọṣa iroyin to n kaakiri ni pe aisan itọ ṣugar ti awọn oloyinbo n pe ni ‘Diabetes’ lo ṣekupa a.

Gẹgẹ bi awọn iroyin abẹle kan ṣe gbe e, aisan itọ ṣuga yii ti n ba Ọmọọba Adebayọ Adeyẹmi finra fun igba diẹ ki o to di pe ọlọjọ de.

Awọn iroyin ti a gbọ sọ pe o ti n ba aisan yii finra lati bi akoko diẹ sẹyin ki o to di wi pe o dakẹ ni ọjọ Ẹti.

De Gov ja ọpọlọpọ ogun nipa ilera rẹ to si bori – Gomina Makinde

Aworan Ọmọọba Abdulfatai Adeyẹmi ati gomina Ṣeyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Heritageecho.com

Gomina Ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ti fi ẹdun ọkan rẹ han lori iku Ọmọọba Adebayọ Adeyẹmi ẹni to fi igba kan ri yan si ipo alaga ajọ owo ifẹyinti ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Ọyọ.

Ninu atẹjade kan eyi ti agbẹnusọ rẹ, Sulaimon Ọlanrewaju, fi sita, Gomina Makinde ni adanu nla gba a ni iku rẹ jẹ.

Gomina Makinde ni ọpọlọpọ ogun nipa ilera rẹ ni oloogbe Adebayọ ja to si ṣẹgun. O ni o ṣenilaanu pe nigba ti awọn to yii ka ro pe ohun gbogbo ti yanju ni ẹlẹmi wa gba a.

“Mo ba awọn ẹbi Ọmọọba Adeyẹmi, awọn eeyan ilu Ọyọ, ẹgbẹ oṣelu PDP ati ẹkun idibo apapọ Ọyọ kẹdun lori iku rẹ.”

Ọjọ́ ìbí Adebayo, ọmọ Alaafin Oyo, Olayiwola Adeyemi III ku ọ̀la ló jáde láye

Ọmọọba Adebayọ pẹlu baba rẹ Alaafin Adeyẹmi III

Oríṣun àwòrán, others

Owurọ Ọjọ Ẹti ni iroyin jade pe Adebayọ, ọmọ Alaafin Adeyẹmi jade laye.

Iṣẹlẹ iku rẹ waye ni nnkan bii wakati mẹrinlelogun si ayajọ ọjọ ibi rẹ to yẹ ko waye ni ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹsan an oṣu kejila ọdun 2023.

Awọn to sun mọọ sọ pe ile iwosan nla UCH ni ilu Ibadan lo dakẹ si.

Oloogbe naa,Ọmọọba AbdulFatai Adebayo Adeyemi ti ọpọ eeyan mọ si "D-GOV", jẹ ọkan lara awọn ọmọ Alaafin Ọyọ ana, (Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi III).

Ni ọdun 2022 ni Alaafin Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta funrarẹ jade laye.

Ọmọọba Adebayọ pẹlu baba rẹ Alaafin Adeyẹmi III

Oríṣun àwòrán, others

Ọjọ Abamẹta ni Ọmọọba Adeyẹmi i ba pe ẹni ọdun mẹtadinlaadọta, amọ iku wọle mu u lọ ni owurọ ọjọ Ẹti.

Iroyin ti a gbọ sọ pe nnkan bii agogo mejila oru kọja iṣẹju marun un ni wọn gbe de ile iwosan nla UCH lọjọ Ẹti ki o to ku ni agogo mẹrin idaji ku iṣẹju mẹwaa.

Iku oloogbe naa la gbọ pe o ti da iporuru ọkan si awọn ẹbi Alaafin Ọba Adeyẹmi ati ilu Ọyọ lapapọ bayii.

Aworan ọkan lara awọn to sunmọ oloogbe naa to tufọ rẹ

Oríṣun àwòrán, screenshot

Ọkan lara awọn arakunrin rẹ, Ọmọọba Akeem Adeyemi Skimeh naa ti kede iṣẹlẹ naa lori itakun ayelujara.

O ni, iroyin to bani ninu jẹ gba ni iroyin iku ọmọọba Adebayọ Adeyẹmi jẹ.

"Arakunrin wa ti o jẹ ọmọ Alaafin ana, Ọmọọba AbdulFatai Adebayo Ayinde Adeyemi ti ọpọ eeyan mọ si "D-Gov" ni iroyin sọ wi pe o jade laye l'owurọ oni. O di oloogbe lẹyin wahala to ba finra lọwọ aarun itọ ṣuga fun ọdun marun un gbako. "

Satide ọjọ kẹsan an oṣu kejila ọdun yii ni ayẹyẹ ọjọ ibi Oloogbe naa, ṣugbọn ọlọjọ de saaju ọjọ ibi to gbero lati fi ṣe ayẹyẹ ọdun kẹtadinlaadọta loke eepẹ.

Aworan ipolongo ti Adebayọ Adeyẹmi ṣe lasiko to n dije fun ibo.

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Adebayọ ni mọlẹbi Alaafin Adeyẹmi keji ti yoo jade laye lẹyin ipaoda rẹ.

Iroyin ti kọkọ gbe e ni oṣu keje ọdun 2022 pe Olori Kafayat, ọkan lara awọn olori Alaafin Adeyẹmi kẹta pẹlu jade laye.

Aworan oloogbe Adebayọ Adeyẹmi

Oríṣun àwòrán, others

Ọmọọba Adebayọ lo ṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 2015 lati du ipo aṣoju ẹkun idibo ilu Ọyọ ninu eto idibo si ile igbimọ aṣofin kekere l'Abuja, ṣugbọn o padanu ipo naa si ọwọ arakurin rẹ, Ọmọọba Akeem Adeyemi to wọle fun saa ikeji l'ọdun 2019.

Gomina Ṣeyi Makinde yan oloogbe naa sipo gẹgẹ bii alaga ajọ to n mojuto owo oṣiṣẹfẹyinti ni ijọba ibilẹ ninu saa akọkọ iṣejọba rẹ.