Ọlọ́pàá tó ń tọrọ owó lọ́wọ́ arìn ìrìnàjo wọ gàù

Oríṣun àwòrán, X
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti kede sita ọwọ ti tẹ ọlọpaa ti fọnran lori ayelujara safihan bi o se n bere owo lọwọ obinrin arin irinajo lori ọkada lati Netherlands.
Ikede yii ni Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo gbe soju opo ayelujara X lọjọ bọ ọsẹ yii , ti wọn si ni ọlọpaa yoo koji ijiya fun iwa naa.
“Fọnran to safihan iwa to ba wa ninu jẹ ọlọpaa kan loju ọna Moniya- Iseyin ni a ti yẹwo.
“Gbpgbo awọn ọlọpaa to wa ninu fọnran naa ni ọwọ ti tẹ, ti wọn yoo si foju ba ofin.”
Ninu fọnran naa, ọlọpaa da obinrin arin irinajo lori ọkada naa duro, to si bere pe nibo lo ti n bọ ati pe ibo lo n lọ.
Obinrin naa da lohun pe lati orilẹede Netherlands ni oun ti wa, ti oun si n lọ Abuja , eyi to ya awọn ọlọpaa meji naa lẹnu.
Ọlọpaa naa kọnu si obinrin arin irinajo naa pe “ki lo ba oun mu bọ? Ki lo fo fẹ fun mi? O ya wa nnkan fun mi,”
Arin irinajo ni ọrọ naa ko kọkọ ye arin irinajo, ti ọlọpaa naa si ni lati mọlẹ fun pe ko fun lowo, ti obinrin naa si bere pe fun kinni.
Fọnran to le ni isẹju kan yii lo fa rogbodiyan lori ayelujara, ti ọpọ si bẹrẹ si ni bu ẹnu atẹlu iwa awọn ọlọpaa naa.















