Forbes kéde Ngozi Okonjo-Iweala, Mo Abudu, àwọn obìnrin méjì míràn láti Áfíríkà lára àwọn obìnrin 100 tó lẹ́nu jùlọ lágbáyé

Oríṣun àwòrán, getty Images/MASI LOSI
Iwe iroyin Forbs ti kede obinrin ọgọrun un ti wọn lagbara julọ lagbaye fun ti ọdun 2023.
Ọdọdun ni Forbs maa n kede orukọ awọn obirin ti wọn lagbara naa latari ipa ti wọn n ko lagbagbe wọn ati lagbaye.
Ni ti ọdun yii, ọmọ ilẹ adulawọ mẹrin, ti ọmọ Naijiria meji wa ninu wọn ni Forbs kede.
Awọn obinrin mẹrin naa ati ohun to yẹ ki o mọ nipa wọn ree.
Ngozi Okonjo Iweala, Naijiria

Oríṣun àwòrán, getty images
Ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa, ọdun 1954 ni wọn bi Okonjo Iweala ni ilu Ogwashi-Ukwu, nipinlẹ Delta.
Baba rẹ, Ọjọgbọn Chukwuka Okonjo, ni Ọba ‘Obi’ lati idile Obahai niluu naa.
O lọ silẹ alakọbẹrẹ St. Anne's School, ni Molete ati International School Ibadan, niluu Ibadan.
Lati ibẹ lọ o tẹkọ leti lọ silẹ Amẹrika, nibi to ti kẹkọọ ni fasiti Harvard nipa eto ọrọ aje, ko to tun tẹsiwaju nilẹ naa.
O ṣiṣẹ ni banki agbaye ‘world bank’ fun ọdun marundinlọgbọn gbako nibi to ti goke agba titi de ipo igbakeji adari ile ifowopamọ naa.
Laarin ọdun 2003 si 2006 ati laarin 2011 si 2015, o ṣiṣẹ sin ijọba Naijiria gẹgẹ bii minisita.
Mo Abudu, Naijiria

Oríṣun àwòrán, getty Images
Ilu Hammersmith, ni West London ni wọn Abudu si nilẹ Gẹẹsi amọ ipinlẹ Ondo ni Naijiria ni orisun rẹ.
Oun ni akọbi ninu ọmọbirnin mẹta ti awọn obi rẹ bi.
O kẹkọọ ni Ridgeway School, MidKent College, ati West Kent College nilẹ Gẹẹsi ko to tẹsiwaju ni fasiti Westmisnter niluu London.
Ojẹ ọkan lara ọmọ ẹgbẹ British Psychological Society nilẹ Gẹẹsi.
Abudu ni oludasilẹ ileeṣẹ Ebonylife TV, eyii to da silẹ lọdun 2006 amọ ọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 2013 ni ileṣẹ naa gbohunsafẹfẹ fun igba akọkọ.
Samia Suluhu Hassan, Tanzania

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Samia Suluhu Hassan jẹ oloṣelu, oun si ni Aarẹ orilẹ-ede Tanzania lẹyin to gori alefa lọdun 2021.
Inu oṣu Kinni, ọdun 1960 ni wọn bi obinrin naa lagbegba Zanziba.
Oun ni Aarẹ obinrin akọkọ lorilẹ-ede Tanzania.
Ko to di Aarẹ, o ti ṣe igbakeji Aarẹ lati ọdun 2015 si 2021 ko to gori alefa, o si ti di oniruru ipo mu ṣaaju asiko rẹ lori aga Aarẹ.
Mpunni Madisa, South Africa

Oríṣun àwòrán, MASI LOSI
Ọdun 1979 ni wọn bi oniṣowo Nompumelelo Thembekile Madisa ni Mohlakeng, ni iwọ oorun Gauteng, lorilẹ-ede South Africa.
Lọjọ kẹjọ, oṣu, Kẹta, ọdun 2019 lo di adari fifdihẹ ileeṣẹ Bidvest Group gẹgẹ bii ọmọ adulawọ ati obinrin akọkọ ti yoo di ipo naa mu.
O kẹkọọ ni Sancta Maria Junior High ati Mondeor High School.
Madisa ti ṣiṣẹ kaakiri, o si ti di gbajumọ lawujọ awọn obirin to lẹnu laarin awọn obirin lagbaye.
Lara awọn ami ẹyẹ ti Madisa ti gba ni ọkan lara awọn obinrin to lagbara ju lagbaye ti iwe iroyin Fortune ati Sunday Times fun.












