Frank Kokori, èèkàn láàrín àwọn tó jà fún ìdápadà ìjọba alágbádá ní Nàìjíríà jáde láyé

Oríṣun àwòrán, others
Ọkan gboogi lara awọn aṣiwaju ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria nigbakan ri, Frank Kokori ti dagbere faye.
Frank kokori gẹgẹbi a ṣe gbọ jade laye ni owurọ Ọjọbọ.
Ohun ti a gbọ ni pe ile iwosan aladani kan to wa ni ilu Warri ni ipinlẹ Delta lẹkun aringbungbun gusu Naijiria nibi to ti n gba itọju fun aisan kidinrin lo dakẹ si.
Oloogbe Kokori fi igba kan ri jẹ akọwe agba fun ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ẹka epo rọbi ati afẹfẹ gaasi nigba aye rẹ.
Kokori jẹ ọkan gboogi lara awọn ọmọ ẹgbẹ ajafẹtọ NADECO nigba aye rẹ.
Ẹgbẹ NADECo yii lo lewaju gbigbena ija woju awọn ijọba ologun lorilẹede Naijiria lati da ijọba pada fun awọn oloṣelu.
Ni ọjọ to yẹ ki gbajugbaja ajafẹtọ araalu naa ṣe ayẹyẹ Ọjọ ibi ọgọrin ọdun rẹ lo dagbere faye.













