Ṣe lóòtọ́ ni ìjọba àpapọ̀ ya ₦10b sọ́tọ̀ fún àtúnṣe ilé Femi Gbajabiamila nínú ètò ìṣúná ọdún 2024?

Oríṣun àwòrán, @femigbaja
Akọwe ijọba Naijiria, Femi Gbajabiamila ti sọ pe irọ ni iroyin to ni owo ti iye rẹ jẹ biliọnu mẹwaa naira ni won ya sọtọ lati ṣatunṣe ile oun ninu eto iṣuna ọdu 2024.
Gbajabiamila lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan loju opo X rẹ.
Ṣaaju ni awọn iroyin kan ti kọkọ sọ pe biliọnu mẹwaa naira ni ijọba apapọ ya sọtọ lati ṣatunṣe ile akọwe ijọba naa ninu eto iṣuna ọdun to n bọ.
Lẹyin iroyin naa ni ọpọ ọmọ Naijiria bẹrẹ si n fi erongba wọn lede, ti wọn si n fapa janu lori igbesẹ ọhun.
Ọpọ ninu awọn eeyan naa lo bu ẹnu atẹ lu Aarẹ Bola Tinubu pe inakuna lo n na owo Naijiria.
Ọgbẹni Gbajabiamila ti wa sọrọ soke pe ko si otitọ kọkan ninu iroyin ọhun.
Ṣe lootọ ni ijọba Naijira ya ₦10b sọtọ fun ile Gbajabiamila?
Iwadii ti fi han pe ko si otitọ ninu awọn iroyin naa.
Ninu ọrọ akọwe ijọba ọhun, o ni awọn owo ti iroyin sọ pe wọn ya sọtọ fun oun wa fun atunṣe ile Aarẹto wa ni Dodan Baracks ati ile igbakeji Aarẹ to wa niluu Eko.
“Ile ara mi ni mo n gbe”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ninu atẹjade naa ni Gbajabiamila ti sọ pe “Mo ti ri awọn iroyin kan lori ayelujara nipa eto iṣuna ọdun 2024, paapaa labẹ ile akọwe ijọba si Aarẹ.
“Akoko ti to lati fesi si awọn iroyin naa ati lati jẹ ko ye awọn araalu pe ko si aye kankan fun atunṣe ile akọwe ijọba si Aarẹ ninu abadofin naa.
“Ile ara mi ni mo n gbe.”
Gbajabiamila sọ pe ijọba to wa lode ko fi ohunkohun pamọ fun awọn araalu lo jẹ ko fi abadofin naa lede fun gbogbo ọmọ Naijiria amọ o tọ ki awọn araalu maa ṣora wọn nipa awọn iroyin ti wọn yoo maa gbe kiri.














