Owó ìsákọ́lẹ̀ fa làásìgbò láàrín àwọn Hausa nílùú Babanla ní Kwara

Oríṣun àwòrán, Government House
Owo iṣakọlẹ gbigba da rogbodiyan, ija ajakuakata silẹ laarin awọn ọmọ Hausa to n gbe niluu Babanla, nijọba ibilẹ Ìfẹ́lódùn, nipinlẹ Kwara.
Ọpọ lo farapa yannayanna lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ Kẹta, oṣu Kejila, ọdun 2023 ti isẹlẹ yii waye.
Laasigbo naa ko si ti dopin titi di oni ọjọ kẹfa, Wesidee sugbon ijọba Kwara ti da awon omo ogun soja si ilu naa ati agbegbe rẹ lati da abo bo ẹmi awọn olugbe.
Ki lo fa rògbòdìyàn naa
Iroyin to tẹ Ileeṣẹ BBC leti ni pe, idaji ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni wahala ọhun kọkọ bẹrẹ laarin awọn janduku Hausa ati eeyan Ọba Hausa iluu Babanla, ti wọn si bẹrẹ si fi oniruuru ohun ija oloro le ara wọn kiri.
Ọkan lara olugbe ilu naa, Barisita M.O Yusuf, salaye pe, awọn Hausa ilu Babanla ni wọn pin ara wọn si meji ti wọn si n jẹ ọba Hausa lọtọọtọ.
Gẹgẹ bi alaye rẹ, Ọba igun akọkọ lo ni ki gbogbo awọn Hausa to n gbe ni iluu naa maa san owo iṣakọlẹ fun oun ni gbogbo igba ti wọn ba ti lọọ taja lọja wọn. O ni wọn gbọdọ maa san ẹgbẹrun kan Naira gẹgẹ bii owo iṣakọlẹ.
Eyi lo mu ki awọn igun keji yari ti wọn si ni awọn ko ni san owo kankan ti wọn si mu ẹjọ ọba Hausa naa lọ sọdọ Ọba iluu Babanla.
Ọba iluu Babanla si paṣẹ ki wọn lọọ mu ọba Hausa to ni ki wọn maa san iṣakọlẹ pẹlu tipatipa.
O tẹsiwaju pe, mimu ti wọn mu ọba awọn Hausa naa, lo mu ki awọn eniyan rẹ dide ti wọn si n beere fun pe ki wọn fi ọba awọn silẹ, ni awọn igun Hausa mejeeji ba bẹrẹ ija igboro laarin ara wọn ti ọpọ si farapa yannayanna.
Gbogbo awọn alaisẹ ilu naa, yala Yoruba tabi Hausa ni wọn si n sa kijo kijo lati doola ẹmi ara wọn.
Kete ti iṣẹlẹ naa bẹrẹ ni Gomina Ipinle Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti pasẹ ki awọn batalionu soja kọja sibẹ lati fopin si rogbodiyan naa.
Ki ni igbesẹ awọn agbofinro ati ibi ti ọrọ naa de duro
BBC kan si alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, Ẹjirẹ Adetoun Adeyemi, lati mo ibi ti iṣẹlẹ naa de duro.
Alukoro ọhun fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni iwadii si n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa ati pe ohun gbogbo ti pada bọ sipo niluu ọhun nitori pe awọn ẹsọ alaabo to fi mọ awọn ọmọ ologun ti gbakoṣo iluu naa.















