Ohun gbogbo ti bàjẹ́ kọjá àlà nílé ìwòsàn Gaza bí àkọlù ṣe ń tẹ̀síwájú - Hamas

Oríṣun àwòrán, EPA
Ileewosan Nasser nilu Khan Younis lapa guusu Gaza ni awọn aworan kan ti jade to ṣafihan bi awọn to n gba itọju ṣe sun silẹ laarin ẹjẹ lẹyin akọlu awọn ọmọgun Israel loru mọju.
Agbẹnusọ ileeṣẹ eto ilera ti Hamas n dari nibẹ, Ashraf al-Qudra, to ni ohun gbogbo ti bajẹ kọja ala nileewosan naa ati wipe oku mẹtalelogoji ni wọn ti ko wọ ileewosan naa laarọ ọjọ iṣẹgun nikan.
Al-Qudra wi pe “ko si eto ilera to le doola ẹmi eeyan lawọn ileewosan to wa lapa guusu Gaza ati pe awọn ileewosan o lee kapa iye awọn to farapa ati irufẹ ifarapa ti wọn ni”.
O fikun pe awọn ọkọ ti wọn fi n gbe alaisan lo nira fun lati de awọn aaye tawọn to farapa wa.
Eyi lo n waye lẹyin ti Israel wi pe awọn ọmọ ẹgbẹ Hamas ni awọn dojukọ ti ko si nii fi bẹẹ si ipalara fun awọn araalu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Israel ṣe akọlu si Lebanon lẹyin ti wọn fi ado oloro ranṣẹ si Israel
Israel ti wi pe awọn ọmọgun ofurufu ilẹ naa lo ti ṣe akọlu sawọn aaye ni Lebanon to jẹ ibudo awọn Hexbollah ni idahun si oko ija ti wọn sọ ranṣẹ si Israel lati ibode apa ariwa ilẹ naa.
Agbẹnusọ IDF, Daniel Hagari, wi pe “ibudo awọn agbesunmọmi, oriko ipamọ wọn ati awọn aaye ti wọn n ko ohun ija pamọ si” ni wọn kọlu.
Lati igba ti ogun naa ti bẹrẹ ninu oṣu kẹwa, ibode apa ariwa Israel ni Hezbollah, ẹgbẹ to ni atilẹyin orilẹede Iran, ti n ṣe akọlu si.
Bakan naa ni ẹgbẹ Hamas wi pe awọn naa fi ado oloro ranṣẹ si Israel lati Lebanon.
Ẹgbẹlẹgbẹ awọn araalu ni Israel ti ko kuro ni agbegbe naa bo tilẹ jẹ pe aawọ to n waye nibẹ ko tii di ogun taara.

Ẹẹdẹgbẹta ọna inu ilẹ ti Hamas n lo la ti bajẹ - Ọmọgun Israel

Lakoko ifọrọlede ajọ ologun ilẹ Israel ni Ọgagun Richard Hetch ti wi pe “lati igba ti ogun yii ti pada bẹrẹ, a n tẹsiwaju igbogun ti Hamas jakejado Gaza.
“A n doju kọ gbogbo ohun to n mayedẹrun fun wọn, paapaa awọn ọna inu iho ilẹ ti wọn n lo. A ti ri to ẹgbẹrin ninu awọn ọna yii ti a si ti ba ẹẹdẹgbẹta jẹ ninu wọn.
“A ko ri irufẹ odi ti wọn mọ yira wọn ka yii ri.
“Ni bi a ṣe ntẹsiwaju ninu akọlu yii, a n gbiyanju lati ri pe awọn araalu ko fi ara pa leyi to mu ki awọn ọmọgun wa o maa lọ lati ojule si ojule.”















