'Google Map' kìí ṣe àwáwí bí o bá ṣìnà l’Eko, o máa fojú winá òfin – Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ fun awọn awakọ pe ki wọn ṣetan lati foju wina ofin ti ọwọ ba tẹ wọn pe wọn gba ọna ti ko tọ nitori aṣiṣe Google Map.
Ọrọ naa lo waye lẹyin ti awakọ kan, Oyiga Micheal sọ lori ayelujara pe awọn ọlọpaa mu oun lagbagbe Ijesha, niluu Eko lori ẹsun pe oun n lo ẹrọ Google Map naa.
Micheal sọ loju opo X rẹ “Ọlọpaa ti mu mi ni Ijesha”
“A lo ẹrọ Google Map lasiko ti a n gbiyanju lati wa ọna lasiko ti a n lọ sile, ni kete ti a fẹ ya ni Ijesha, wọn ni a gba ọna ‘one way,’ wọn si dunkoo lati jo taya ọkọ wa.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
“Wọn ti gba ọkọ wa o, wọn kọ lati fi wa silẹ, ẹ jọwọ a nilo iranlọwọ.”
Micheal ṣalaye pe awọn ọlọpaa naa ri awọn lasiko ti awọn n bọ amọ wọn ko sọ fun awọn pe ko si ọna nibi ti wọn n lọ.
O fẹsun kan awọn ọlọpaa naa pe wọn mọọmọ jẹ ki wọn wọn wọ ọna ‘one way’ ọhun tan ki to mọọmọ fi ṣikun ofin mu wọn.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn ọlọpaa naa ni awọn gbọdọ san N30,000 ki wọn to fi awọn silẹ.
Amọ nigba ti yoo fesi, alukoro ileeṣe ọlọpaa Eko, Benjamin Hundeyin ni ko si awawi kankan fun ọkunrin naa lati gba ọna ‘one way.’
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Hundeyin sọ pe “Aimọ kii ṣe awawi labẹ ofin, bẹẹ naa ni Google Map kii ṣe awawi, fara rẹ balẹ ki o jẹ ki ofin ṣiṣẹ rẹ.”
Ọpọ eeyan lo ti fi erogngba wọn lede lori esi agbẹnusọ ọlọpaa naa, ti pupọ ninu wọn si bu ẹnu atẹ ohun ti agbẹnusọ ọlọpaa ọhun sọ.














