Wo ọ̀nà tuntun tí àwọn afurasí ń lò láti gbé ògùn olóró

Aworan awọn afurasi naa

Oríṣun àwòrán, ndlea

Ọwọ ṣikun ajọ to n gbogun ti lilo oogun oloro ni Naijiria NDLEA ti tẹ awọn afurasi onifayawo oogun oloro kan jakejado Naijiria.

Ninu awọn ti ajọ naa kede pe awọn ri mu lawọn kan to ko oogun oloro sinu agolo ''milo'' ati ọṣẹ ibilẹ eleyi ti wọn gbero lati gbe lọ si Yuroopu,UAE ati Asia.

Femi Babajide to jẹ alukoro ajọ naa lo fidi ọrọ yi mulẹ loju opo wọn ni Facebook.

O ṣalaye pe awọn afurasi yi ko oogun oloro bi methamphetamine ati opioids sinu apo atọwọda ti wọn ran sara ṣokoto jeans ati ninu ọmọ langidi.

Bakan naa lo lawọn tun ribi dena oogun oloro lawọn ileeṣẹ kan tawọn eeyan ti n fẹru ranṣẹ to wa nilu Eko.

Lara ohun ti wọn ri gba nibẹ la gbọ pe Tramadol 225mg ti wọn gbe pamọ sinu apo ṣokoto jeans,igbo ti wọn ko sinu ori ‘’baby’’ ọmọ langidi to n lọ si Dubai ati Tramadol 225mg ti wọn gbe pamọ sinu milo.

O tẹsiwaju pe awọn tun ri awọn oogun oloro kan ti wọn n gbiynaju lati gbe wọ Naijiria lati Florida lorileede America.

Ẹni to lẹru naa arakunrin Daniel Ogi ni wọn sọ pe awọn ri mu ladugbo Akem Shittu Ajao Estate lọjọ Kẹrinlelogun oṣu Kọkanla .

Baba Isalẹ onifayawọ oogun oloro ko si gbaga NDLEA

Gẹgẹ bi Babafemi ṣe sọ, ọwọ NDLEA tun tẹ arakunrin kan ẹni ọdun mẹrindinlọgọta, Okechukwu Ogala to jẹ baba isalẹ to maa n ko awọn ọdọ lati fi ṣe fayawọ oogun oloro lọ si awọn orileede ilẹ Asia.

Ladugbo Mushin nilu Eko yi kanna awọn oṣiṣẹ NDLEA tun gba kilo igbo 393 ni ṣọọbu kan to wa ni Akala ti wọn si gba afurasi oniṣowo oogun oloro kan Justin Enuonye mu.

Wahab Olota toun naa jẹ afurasi oniṣowo oogun oloro ladugbo Adedoja ni Mushina ko si pampẹ ajọ NDLEA.

Ni Ipinlẹ Edo,ọmọ ọdun mejilelogun kan Mson Bunde ni wọn ka mọ ninu ile amọ kan to wa ninu oko ti wọn gbin igbo si.

Kilo ẹgbẹrun mẹfa din diẹ ni wọn ri gba lọwọ rẹ.