Ìjà láàrín tọkọtaya lójú òfúrufú mú kí bàálù balẹ̀ ní pàjáwìrì

Oríṣun àwòrán, Reuters
Iṣẹlẹ yi waye ninu baalu ti nọmba rẹ jẹ LH 772 ti wọn dari pada pe ko balẹ pajawiri ni Delhi orileede India lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kejila.
Pakistan lo kọkọ ro pe ohun yoo ti balẹ ki wọn to dari rẹ pada si Delhi.
Ileeṣẹ iroyin orileede naa kan ANI news jabọ pe wọn gbe igbesẹ yi lẹyin tawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ofurufu naa sọ pe ipa awọn ko ka tọkọtaya yi ti ija wọn si ti bẹrẹ si ni kọja oju lasan.
Idi ree ti wọn fi pe papakọ ofurufu pe awọn fẹ balẹ pajawiri ki ọrọ baa le lojutu.
Lẹyin iṣẹlẹ naa, ileeṣẹ ọkọ ofurufu Lufthansa fi atẹjade sita.
Ninu rẹ wọn sọ pe wọn ja arakunrin naa ati iyawo rẹ bọlẹ ninu baalu naa nigba to balẹ ni Delhi.
Ọmọ orileede Germany ni ọkọ ti iyawo si jẹ ọmọ orileede Thailand.
Bangkok ni awọn mejeji jijọ n lọ lati Germany ti wọn ti gbera.
Lufthansa sọ pe awọn mejeeji tọrọ aforijin ṣugbọn iyawo tẹsiwaju irinajo naa ti ọkọ ko si ba baalu naa rin mọ.
Orileede Germany ni baalu naa ti gbera to si kọkọ fẹ balẹ pajawiri ni Pakistan ṣugbọn ko ribi gba iyọnda lọdọ awọn alaṣẹ.
Ki lo fa ija laarin wọn
Loju opo ayelujara lẹyin ti awọn eeyan ka nipa iṣẹlẹ yi, orisi idi lawọn eeyan n fi ṣọwọ pe o da wahala silẹ laarin lọkọlaya naa.
Amọ eleyi ti wọn fẹran julọ ni pe iyawo ka ọkọ mọ nidi agbere.
Awọn alaṣẹ ko fidi ọrọ yi mulẹ.
Ileeṣẹ ofurufu ti wọn wọ sọ pe awọn ti fa arakunrin naa le awọn agbofinro lọwọ nitori oun ni ko farabalẹ ninu ọkọ baalu ofurufu .
Ko daju boya wọn yoo fi ṣọwọ pada si Germany to ti gbera ni tabi yoo foju wina ofin ni India.
Eyi ti a ri ka ninu atẹjade ileeṣẹ Lufthansa ni pe iyawo ti tẹsiwaju irinajo rẹ lọ si Bangkok pẹlu baalu naa ṣugbọn ọkọ ko tẹle.
Ninu alaye ileeṣẹ ofurufu naa wọn ni ọkọ iyawo lariwo rẹ pọ ti ko si da awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọkọofurufu naa lohun nigba ti wọn ni ko ṣe pẹlẹ.
Wọn lo n pariwo bẹẹ si lo lo ẹrọ iṣana igbalode lighter kan lati fi dana si ara aṣọ ibusun kan.
Wọn ko ṣalaye ibi to ti ri iṣana naa.
Ki lo maa n fa ki baalu balẹ pajawiri
Lẹka irinajo ofurufu orisirisi idi lo maa n ṣe sababi ti wọn fi maa n jẹ ki baalu balẹ nibalẹ pajawiri.
A ti gbọ pe wọn mu baalu balẹ pajawiri lẹyin ti wọn sọ fun arinrinajo kan pe iru ounjẹ to fẹ jẹ ko si lori atẹ to si da ibinu bolẹ.
Koda alaboyun to ri apẹrẹ pe asiko to lati bimọ naa ti mu ki wọn jẹ ki baalu balẹ pajawiri.
Amọ eyi taa mu tọ yin wa yi jẹ kayeefi tori baalu naa balẹ pajawiri nitori pe tọkọtaya kan gbena woju ara wọn ti ija naa si buru debi pe awọn ero inu baalu yoku ko ribi fẹdọ lori oroonro.












