''Ó ṣòro láti rí ẹni tí yóò jàjàyè nínú àwọn 72 tó wà nínú ọkọ̀ bàálù tó já''

Oríṣun àwòrán, EPA-EFE/REX/Shutterstock
Ileeṣẹ ọlọpaa ni Nepal ti ni yoo ṣoro lati ri ẹnikẹni ti yoo jajaye ninu awọn mejilelaadọrin to wa ninu ọkọ baalu to ja ni orilẹede naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Tek Prasad Rai sọ fun BBC pe ko si afojusun pe ẹnikẹni ṣi wa laaye ninu awọn to wa ninu ọkọ baalu naa to ja lulẹ.
O kere tan eniyan mejidinlaadọrin lo gbẹmi mi ti wọn si ti ri oku wọn amọ wọn ṣi n wa eniyan mẹrin.
Titi di asiko yii, wọn ṣi n wa nkan to fa ijamba ọkọ ofurufu naa nitori naa iwadii ṣi n lọ lọwọ.
Aworan to wa nita safihan bi ọkọ ofurufu Yeti Airlines naa ṣe n fo kaakiri oju ofurufu, ki o to jabọ ulẹ.
Awọn arinrinajo mejilelaadọrin lo wa ninu ọkọ ofurufu naa pẹlu awọn oṣiṣẹ inu ọkọ naa.
Nibayii, Olootu orilẹede Nepal ti paṣẹ ki awọn eniyan ya Ọjọ Aje si ọtọ lati ṣedaro awọn to papoda naa.
Ọkọ̀ òfúrufú tó kó èèyàn 72 já lulẹ̀ ní Nepal, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹmi ọpọ eeyan ti sọnu lẹyin ti ọkọ ofurufu kan ja lulẹ lorilẹ-ede Nepal.
Iroyin ni ẹba papakọ ofurufu kan ni aringbungbun orilẹ-ede naa ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Ọkọ ofurufu naa, to jẹ ti ileeṣẹ Yeti Airlines gbera lati Kathmandu si ilu Pokhara ti ọpọ awọn arinrinajo afẹ maa n wa ko to ja lulẹ, to si lana.
Awọn fidio kan lori ayelujara ṣafihan ọkọ ofurufu kan lagbagbe ti ile pọ si, ko to ya bara.
O kere tan, eeyan mejidinlaadọrin ni iroyin fidi rẹ mulẹ pe wọn ti jade laye bayii, nigba ti ọpọ awọn mii si farapa yanayana.
Niṣe ni ọkọ ofurufu naa ja si wẹwẹ
Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa, Divya Dhakal sọ fun BBC pe oun sare digbadigba lọ sibi ti baalu naa ja si.
O ni “Nigba ti mo maa fi de ibẹ, ọpọ ero lo ti peju sibẹ ti eefin nlan kan si n ru jade lati ara ọkọ ofurufu ọhun.”
“Laipẹ si asiko naa ni ọkọ ẹlikọputa kan de sibẹ lati doola awọn eeyan.”
Dhakal fi kun pe “Awakọ ofufurufu ọhun gbiyanju pe ko má ja si aarin ilu nibi ti ọpọ araalu wa.”
Apapọ awọn to wa ninu ọkọ naa jẹ eeyan méjídínláàdọ́rin yato si awọn oṣiṣẹ.
Ninu wọn ni ọmọ ilẹ okeere marundinlogun ati oṣiṣẹ ọkọ ofurufu mẹrin wa.
Ọpọ awọn ọmọ ogun Nepal lo ti wa nikalẹ lati ṣiṣẹ adoola ẹmi nibi ti ọkọ naa ja si.
Amọ ṣa, agbenusọ ileeṣẹ ọmọ ilẹ naa sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe awọn ṣi n reti lati ko ọpọ oku eeyan jade nibẹ nitori ṣe ọkọ ofurufu naa ge si wẹwẹ.












