Àwọn agbébọn yabo ilé Àlùfáà, wọ́n sun òun àti ọ̀pọ̀ dúkìá mọ́lé

Oríṣun àwòrán, Fada Ebube Divine Mercy
Awọn agbebọn ti ṣekupa alufa ijọ katoliiki kan, Isaac Achi, lẹyin ti wọn kọlu ile rẹ lorumọju ọjọ Aiku.
Iroyin ni awọn agbebọn naa dana sun ile rẹ lasiko ti oloogbe ọhun ṣi wa ninu ile naa, iyẹn lẹyin ti gbogbo igbiyanju wọn lati wọ inu ọhun ja si pabo.
Ṣaaju iku rẹ, oloogbe naa ni alufa ijọ St. Peters and Paul Catholic Church to wa ni Kafin-Koro, ni ijọba ibilẹ Paikoro, nipinlẹ Niger.
Ibọn ba alufaa mii lasiko ikọlu naa
Nigba to n fidi iroyin naa mulẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Niger, DSP Wasiu Abiodun sọ pe awọn agbebọn naa tun yinbọn lu alufaa miran lasiko ikọlu naa.
Ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin, o ni “Ni nnkan bii aago mẹta oru ọjọ karundinlogun, oṣu Keji, ọdun 2023 ni awọn agbebọn kan yabo ile alufaa Isaac Achi ti ijọ St. Peters and Paul Catholic Church...”
“O ṣeni laanu pe awọn agbebọn naa gbiyanju lati wọ inu ile alufaa ọhun amọ o sọro fun wọn, eyii to mu ki wọn dana sun ile naa nigba ti alufaa ọhun si wa ninu rẹ.”

Oríṣun àwòrán, Fada Ebube Divine Mercy
“Awọn agbebọn naa tun yinbọn lu alufaa Father Collins, to jẹ alabaṣiṣẹpọ oloogbe ni ejika lasiko to n gbiyan lati sa asala fun ẹmi rẹ.”
Agbẹnusọ ọlọpaa naa fi kun pe awọn ọlọpaa gbera lọ sile naa ni kete ti iṣẹlẹ ọhun to awọn leti amọ awọn kọlọrọsi to ṣiṣẹ ibi naa ti na papa bora lasiko ti awọn yoo fi de ibẹ.
O ni wọn ti gbe oku oloogbe naa lọ sile iwosan bayii.
O pari ọrọ rẹ pe kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Niger, Ogundele Ayodeji ti ran awọn akọṣẹmọṣe ọtẹlẹmuyẹ si agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye lọna ati le tete ri awọn afurasi agbebọn ọhun mu, iwadii si ti bẹrẹ.












