Afurasí Eluyera Wasiu san ẹgbẹ́rùn mẹ́wàá kí wọ́n fi pa aláboyún aya rẹ̀ ní Ogijo- Olọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Abimbola Oyeyemi
Ọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ arakunrin ẹni ọdun marundinlogoji kan ti orukọ rẹ njẹ Eluyera Wasiu fun ẹsun pe o bẹ ọrẹ rẹ, Adeniyi Samuel lati pa iyawo e omo odun mokandinlogbon pẹlu oyun inu rẹ.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn akoroyin, agbẹnuso fun Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun SP Abimbola Oyeyemi, so pe ọwọ ti tẹ awọn afurasi naa.
Abimbola ni awọn kan lo fi ipe sita ti ọga ọlọpa Ogijo nijọba ibilẹ sagamu gbe igbesẹ latari ija to waye laarin Adeniyi Samuel ati ọrẹ re Eluyera Wasiu.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun Abimbola ni lakoko ifọrọwanilẹnuwo, Adeniyi Samuel sọ fun awọn ọlọpaa pe Eluyera Wasiu bẹ oun lati pa iyawo rẹ ti o loyun, Bola Taiwo.
Gege bi o ti sọ, afurasi naa sọ pe Wasiu ṣe ileri lati fun un ni ẹgbẹrun mewaa naira fun iṣẹ naa,
ninu eyi ti o ti fun un ni ẹgbẹrun marun pẹlu ileri lati san iyoku lẹyin ti o baa ti pari iṣẹ naa.
Iwadii awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun fihan pe Wasiu Eluyera ati Bola Taiwo ni wọn ti jọ gbẹ gẹgẹ bi tọkọtaya ṣaaju ariyanjiyan laarin awọn mejeeji ti o mu ipinya wa.










