Babaláwo kú sórí ìyàwó 'pásítọ̀' nílé ìturá ní Ikere-Ekiti

Fadayomi Kehinde

Oríṣun àwòrán, fadayomi kehinde/facebook

Ọrọ buruku, to n tẹrin, ni iṣẹlẹ kan to waye nilu Ikere Ekiti, nipinlẹ Ekiti, lẹyin ti ọkunrin kan kú nibi to ti n ni ibalopọ pẹlu obinrin kan nile itura.

Ọkunrin naa, ti wn pe orukọ rẹ ni Fadayomi Kehinde ‘Ejiogbe’, ni wọn lo jẹ babalawo.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe iṣẹlẹ naa waye ni ọjọ Aje, ọjọ keji, oṣu Kinni, ọdun 2023.

Iroyin ni iyawo oluṣọ agutan ile ijọsin kan ni agbegbe ọhun, ni obinrin ti babalawo ku sori rẹ, eyi to mu ki iṣẹlẹ naa jẹ kayeefi fun gbogbo awọn to wa nibẹ.

Gẹgẹ bi iroyin to n lọ, awọn ololufẹ mejeeji n ni ibalopọ lọwọ ninu yaara ile itura naa, ni ọkunrin naa deede ṣubu lulẹ.

Lẹyin naa ni obinrin ọhun ke gbajare fun awọn oṣiṣẹ ile itura naa.

Wọn ni kiakia si ni wọn gbe ọkunrin naa lọ si ileewosan kan ni agbegbe naa, amọ o ti ku.

Bakan naa ni iroyin ni awọn akẹẹgbẹ babalawo naa sọ pe ‘magun’ lo pa a .

Magun, ni igbagbọ Yoruba sọ pe wọn ma n fi si ara obinrin to ba jẹ iyawo ile, amọ to n yan ale, tabi obinrin ti ọkunrin gbagbọ pe o n yan ale.

Eyi jẹ igbesẹ lati kọ ọkunrin to n ba obinrin naa ni ibalopọ lẹkọọ.

Lẹyin iku Babalawo Fadayomi Ejiogbe, ni iroyin sọ pe awọn ọdọ kan ni adugbo yabo ile ijọsin pasitọ to jẹ ọkọ obinrin naa, ti wọn si ba nkan jẹ́ nibẹ.

Eyi ṣeeṣe ko jẹ pe wọn lero pe pasitọ lo fi magun si ara iyawo rẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Sunday Abutu, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun ileeṣẹ iroyin abẹle, Punch, sọ pe iwadii ti n lọ lori iṣẹlẹ naa.

O ni lootọ ni ọkunrin kan ku si ile itura kan niluu Ikere-Ekiti lọjọ Aje, ti wọn si ti gbe oku rẹ lọ si ibudo igboku pamọ si.

Bakan naa ni ASP Abutu sọ pe wọn ti n fi ọrọ wa obinrin naa ni ẹnu wo fun iwadii nkan to ṣokunfa iku arakunrin naa.