Wọn ti rí òku Ooreoluwa, ọmọ tọkọtaya tí wọ́n dáná sún ni Abeokuta lọ́jọ́ ọdún, wo ohun tí ọlọ́pàá Ogun tún sọ...

Oríṣun àwòrán, Others
Wọn ti ri oku Ọrẹoluwa, ọmọ tọkọ taya ti wọn danu sun lọjọ ọdun
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti ṣawari Ọrẹoluwa, ọmọ tọkọ taya ti awọn agbebọn amookunṣeka dana sun mọ inu ile lọjọ kinni, oṣu kinni, ọdun 2023 ti a wa yii.
Nnkan bi aago meje aabọ aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee la gbọ pe awọn apẹja odo naa kọkọ kofiri oku ọmọkunrin, ọmọ ọdun marundinlọgbọn naa.
Ṣaaju akoko yii, iyẹn lọjọ Aiku, Sannde ni ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ti lọ si odo naa, lati rawọ ẹbẹ si awọn apẹja lati wa oku ọmọ naa, ṣugbọn ti wọn ko rii.
Bankọle sọ pe ki awọn apẹja naa ma ṣe dawọ wiwa oku naa duro, idi ree ti wọn fi l'awọn apẹja yii wa ni ojufo lati mọ ibi ti oku naa wọle sii.
Ọrẹoluwa ati ọmọ ọdọ wọn ni iroyin fi to wa leti pe awọn amookunṣeka naa lọ ju sinu odo to wa loju ọna Adigbẹ si Ọbada-Oko niluu Abẹokuta, ni kete ti wọn ṣeku pa baba ati baba rẹ.
Ta ni Taiwo Idowu tó rí òkú Ooreoluwa àti pe bawo lo ṣe rí í?
Idowu Taiwo, ọkan lara awọn apẹja odo yii ṣalaye pe latigba ti ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe ka maa wa oku ti awọn amookunṣeka ju sodo l'awọn naa ko ti dawọ duro.
O ni bi oun ṣe de odo laarọ ana lati bẹrẹ sii pa ẹja, loun kofiri oku kan ti wọn de ni ọwọ àti ẹsẹ, toun si ni igbagbọ pe ẹni ti wọn n wa ni.
Taiwo ni niṣe ni oku Ọrẹoluwa le tente sori odo nitosi irinṣẹ ti wọn fi n pa ẹja. O ni loju ẹsẹ loun ti sọ fawọn eeyan lati wa nọmba ẹrọ ibanisọrọ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lati fi to o leti.
O ni kete ti alukoro ọlọpaa naa ti gbọ, lo ti ranṣẹ pè awọn ọlọpaa wọn, ti wọn si wa gbe oku naa lọ mọṣuari ọsibitu jẹnẹra to wa ni Ijaye niluu Abẹokuta.
Mọ̀ síi nípa Ooreoluwa, ọmọkunrin awọn tọkọtaya ti wọ́n pa ni Abeokuta?
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Fasiti Babcock to wa ni Ikẹnnẹ, ipinlẹ Ogun ni Ọrẹoluwa ti kẹkọọ jade lọdun to lọ lọhun, ti wọn si lo n gbiyanju lati lọ kawe sii ni fasiti Ibadan.
Ẹnikan to pe orukọ rẹ ni Sunday Ṣaanu, ẹni to loun ati Arabinrin Olubukọla Fatinoye jọ jade ile-ẹkọ girama Liṣabi to wa ni Idi Aba lọdun 1988 sọ pe oun loun n ba Ọrẹoluwa wa ọna bi yóò ṣe wọ Fasiti Ibadan lati ṣe Masters rẹ.

Oríṣun àwòrán, others
Ṣaanu jẹ ko di mimọ pẹ ti Arabinrin naa ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi aadọta ọdun, iyẹn ninu oṣu kẹfa, ọdun to kọja lo ran Ọrẹoluwa wa ba oun niluu Ibadan, toun si gbiyanju agbara oun lati wa ọna bi yoo ṣe wọ Fasiti Ibadan.
Ni bayii, CP Lanre Bankọle ti ṣeleri wi pe awọn yoo rọwọ to awọn amookunṣeka naa, ti wọn yoo si fi wọn j'ofin laipẹ.
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni iṣẹlẹ ọhun ṣi n jẹ kayeefi nla fun ọpọ awọn to ti gbọ, paapaa awọn mọlẹbi Ọgbẹni Kẹhinde Fatinoye ati Arabinrin Bukọla Fatinoye .
Won ti sin oku arakunrin Kehinde to jẹ ọga agba nile ifowopamọsi Central Bank of Nigeria ni Abeokuta ati ti aya rẹ Olubukola to jẹ ọga agba nile ẹkọ giga Fasiti olohun ọgbin ni Abeokuta, iyen Federal University of Agriculture, Abeokuta nilan ẹsin onigbagbọ.

Wọ́n ti sin òkú àwọn tọkọtaya méjèèjì tí àwọn oníṣẹ́ ibi dáná sun ní Abeokuta
Bi ẹlẹkun ṣe n sunkun, bẹẹ l’awọn miran n gbera ṣanlẹ nibi ti wọn ti sinku awọn oloogbe mejeeji yii ni itẹku to wa lagbegbe Lantoro niluu Abẹokuta.
Ẹsẹ ko gbero ni ṣọọṣi Christ Anglican Church to wa ni Iporo Ake niluu Abẹokuta, nibi ti wọn ti gbe oku wọn wọ lati ṣe ẹyẹ ikẹhin fun wọn.
Rẹfurẹndi S.K Oyewale to lewaju isin ẹyẹ ikẹhin naa ṣapejuwe awọn oloogbe naa gẹgẹ bi oniwa tutu ti wọn n ran iṣẹ iranṣẹ ijọ naa lọwọ ni gbogbo igba, koda to ni wọn kii fi isin ṣere.
Kini Alufaa ile ijosin sọ nipa awọn mejeeji?
Alufaa yii sọ pe inu ṣọọṣi naa ni wọn ti kuro ko to di pe iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ loru mọjumọ, to si rawọ ẹbẹ s’awọn agbofinro lati tọpinpin iṣẹlẹ ọhun, ki ọwọ le tẹ gbogbo awọn to lọwọ ninu iku naa.
Ara, ọrẹ, ojulumọ atawọn abanikẹdun la gbọ pe wọn wa nibi eto isinku naa lọjọ Aje, Mọnde ana.
Pupọ awọn to wa nibi itẹkuu naa ni wọn n ṣepe rabandẹ rabandẹ f’awọn to ṣiṣẹ buruku naa, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe awọn ti wọn pa yii jẹ gboogi to n ṣe iranlọwọ f’awọn eeyan, paapaa ninu mọlẹbi.
Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ agbẹnusọ f’awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun nigba to n sọrọ sọ pe iṣẹlẹ naa ko yatọ si ti agbanipa, to si ni ọga awọn ti paṣẹ pe ki ẹka ileeṣẹ wọn to n ṣe iwadii ọran, iyẹn State Criminal Investigation Department (SCID) tẹsiwaju iwadii, ki ọwọ le tẹ awọn amookunṣeka ọhun.

Ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí àwọn tó dáná sun tọkọtaya mọ́lé lọ́jọ́ ọdún tuntun
Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni iṣẹlẹ naa ṣi n jẹ kayeefi fun gbogbo awọn araalu Abẹokuta ati agbegbe ẹ nipinlẹ Ogun, paapaa awọn to gbọ sii, sibẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti f’idi rẹ mulẹ pe gbogbo awọn to lọwọ ninu iwa ika naa ni yoo f’oju wina ofin.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi n’igba to n sọrọ kọminu lori iṣẹlẹ aburu ọhun.
To si l’awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii, ati pe ọwọ ti tẹ ẹnikan lori bi wọn ṣe dana sun t’ọkọ t’iyawo naa mọle, ti wọn tun ji awọn ọmọ wọn gbe salọ.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ BBC YORUBA lọwọ, a gbọ pe ni kete ti ọkọ ati iyawo naa, Ọgbẹni Kẹhinde Fatinoye ati Arabinrin Bukọla Fatinoye de lati ibi isin wọnu ọdun tuntun l’awọn amookunṣeka naa lọ ka wọn mọle ni nnkan bi aago mẹta ọru, ko to di pe wọn dana sun wọn mọle.












