Sunday Igboho fẹ́ ṣe ìwọ́de n'Ibadan lórí ọkùnrin tó dàwátì 'sọ́wọ́ Amotekun'

Oríṣun àwòrán, others
Ọkan pataki lara awọn to n ja fun idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa, Sunday Adeyemo Igboho, ti kesi awọn ọmọ ilẹ Yoruba, lati darapọ mọ fun iwọde lori bi ọmọkunrin kan ṣe di awati.
Ọmọkunrin naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Bobola, ni iroyin sọ pe awọn ẹbí rẹ ko ri, lati ọjọ Ẹti, ọgbọnjọ, oṣu Kejila, ọdun 2022.
Eyi waye lẹyin ti iroyin sọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ Amotekun nilu Ibadan, yabo ile ọdọmọkunrin naa, ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn.
Ajijagbara fun idasilẹ Yoruba Nation, Sunday Igboho, ti kọkọ fi iroyin nipa iṣẹlẹ si ori ayelujara Instagram rẹ lọjọ kinni, oṣu Kinni, ọdun 2023. O si fun ijọba ipinlẹ Oyo ati ajọ Amotekun ni gbedeke wakati mẹrinlelogun, lati wa ọmọkunrin naa ri.
Ṣaaju ni ẹnikan to pe ara rẹ ni ẹgbọn arakunrin naa, Martins Oreoluwa Obong, sọ pe ni ọjọ Ẹti, ọgbọnjọ, oṣu Kejila, ọdun 2022, ni awọn oṣiṣẹ Amotekun, wọ ile ti aburo oun n gbe ni agbagbe Apata, nilu Ibadan.
O ni lati igba naa si lo ti di awati.
Sunday Igboho ni oun kesi gbogbo awọn to ba nifẹ lati darapọ mọ iwọde naa, lati korajọ pẹlu oun, ni ọfiisi gomina ipinlẹ Oyo, lowurọ Ọjọru.
“Niwọn igba ti ijọba ipinlẹ Oyo, ati Amotekun, ti kọ̀ lati da wa lohun, a ni lati gbe igbesẹ.”
Gẹgẹ bi iroyin naa, ni bi aago mẹrin aabọ owurọ, ni awọn oṣiṣẹ Amotekun wọ inu ile naa, ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn.
“Bi aburo mi ṣe gburo ibọn, ni oun ati ọrẹ rẹ kan raaye sa jade, ti awọn Amotekun si sa tẹle wọn.
“Bi wọn ṣe n le wọn, ni wọn n yinbọn.”
Iroyin ọhun tẹsiwaju pe awọn ara adugbo sọ pe awọn ri awọn oṣiṣẹ Amotekun, to wa si ile ẹkọ kan nitosi ibẹ lati gbe oku eeyan kan.
“Wọn ni adigunjale ni awọn pa.”
Ẹgbọn ọmọkunrin ti wọn n wa ọhun tun sọ pe ọrẹ rẹ mẹrin ni awọn Amotekun mu, ti wọn si fi ẹsun idigunjale kan wọn.
O ni wọn ti ko wọn lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa ni adugbo Eleyele nilu Ibadan.
Titi di asiko yii, ileeṣẹ Amotekun tabi ọlọpaa nipinlẹ Oyo, ko ti sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ yii.
Igba akọkọ si kọ re e , ti awọn araalu fi ẹsun kan awọn oṣiṣẹ ajọ alaabo Amotekun nipinlẹ Oyo, pe wọn yinbọn pa araalu lai ṣẹ̀.














