Nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa R'Bonney, ọmọ US tó di Miss Universe 2022

R'Bonney Gabriel

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọmọ orilẹ-ede USA, R’Bonney Gabriel, ti gba ade gẹgẹ bi Miss Universe fun ọdun 2022.

O gba ade naa lọwọ Harnaaz Kaur Sandhu, ọmọ orilẹ-ede India to gba a lọdun 2021.

Ọjọ Aiku, ọjọ karundinlogun, oṣu Kinni, ọdun 2023, ni awọn omidan to rẹwa julọ kaakiri awọn orilẹ-ede agbaye, korajọ pọ silu New Orleans, US, fun ikọkanlelaadọrin eto naa.

Apapọ orilẹ-ede mẹrinlelọgọrin lo kopa nibi idije bii ọrọ apilẹsọ, ifọrọwanilẹnuwo, aṣọ ibilẹ, ati awọn aṣọ alarambara.

Ṣaaju ki wọn o to o kede ẹni to bori, Miss Venezuela, Miss Dominican Republic ati Miss USA, ni omidan mẹta to kẹhin sinu idije naa.

Miss Venezuela lo ṣe ipo keji.

Taa ni R’Bonney Gabriel?

Gẹgẹ bi akọsilẹ to wa ni ori ayelujara Miss Universe, aranṣọ, olukọ aṣọ riran ati arinrin oge, ni R’Bonney.

Ọmọ ọdun mẹẹdogun lo ti bẹrẹ iṣẹ aṣọ riran.

O kẹkọọ gboye ninu ṣiṣe aṣọ l’oge ni Fasiti North Texas lọdun 2018.

Lọwọlọwọ, oun ni ọga agba ileeṣẹ aṣọ rẹ, R’Bonney Nola.

Bakan naa ni R’Bonney tun jẹ olukọ aṣọ riran ni Magpies& Peacocks, ileeṣẹ aranṣọ kan to jẹ ajọ alaanu, ni Houston.

Nibẹ lo ti n kọ awọn obinrin to bọ lọwọ owo ẹru ati iwa ipa ninu igbeyawo, ni aṣọ riran.

R’Bonney sọ pe ilepa oun fun awọn obinrin ati ọmọdebinrin, ni lati ri oun gẹgẹ bi aworan ara wọn, ki wọn o si ti ara oun ni iwuri lati ṣe aṣeyọri ninu gbogbo afojusun wọn.