Àwọn olùjọ́sìn wẹ̀ nínú omi yìyín láti ṣe ayẹyẹ ọdún túntun ni Tokyo

Aworan

Awọn olujọsin tu sita lati ṣe ayẹyẹ ọdun tuntun pẹlu iwẹ ninu omi yiyin, eyi to ti wa lati ọdun mejidinlaadọrin sẹyin.

Ayayọ ọdun tuntun orilẹede Japan lo yatọ si ti gbogbo agbaye, ti awọn si maa gba ọna miiran lati fi ṣe ayẹyẹ ọdun lorilẹede naa.

Ayẹyẹ ìṣetutu Shinto lo ma waye lọjọ Aiku keji oṣu kini ọdun tuntun

Lọdun yin, ogoji eeyan lo kopa ninu iwẹ naa ni idi orisha Teppozu Inari lọsẹ to kọja, ti tọkunrin ati tobinrin wọn, ninu asọ funfun wọn si bọ sinu agbami nla to kufun yiyin.

Iṣetutu Shinto ni lo wa lati wẹ ẹmi awọn araalu, ko si tun alaafia wa lọdun tuntun ti wọn bọ si.

Ọpọ awọn olujọsin si yoo bọ sinu omi naa lati se adura fun ara wọn ati awọn ololufẹ wọn.

Iṣẹju mẹrin pere ni wọn ni lati lo ninu agbami omi yíyin ọhun.

Yoshiko Shibata, obinrin ẹni ọdun marindinlọgọrin to kopa ninu iwẹ naa salaye pe kete ti oun ba ti wẹ tan ni ara oun yoo tuka, ti alaafia yoo si de ba oun.

Shibata ni ọdọdun ni awọn maa wẹ iwẹ naa lati gbadura fun ìlera to peye ni ago ara wọn.

"Ti n ko ba ti wẹ, n ko ni igbagbọ pe ọdun tuntun ti de rárá"

Nigba wo ni ìṣetutu iwẹ Shinto bẹrẹ?

Aworan

Ọdun 1955 ni ìṣetutu naa kọkọ waye nigba ti olori awo wọn tẹlẹ maa fan omi tutu si ara rẹ to ba ti n gbadura

Ọdun yii lo pe ọdun mejidinlaadọrin ti wọn wẹ iwẹ Shinto lorilẹede Japan

Aworan