Agbábọ́ọ̀lù Zambia tẹ́lẹ̀ pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ ajá rẹ̀ mẹ́ta

aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede South Africa ti kede iku agbabọọlu Zambia tẹlẹ, Philemon Mulala lẹyin ti awọn aja rẹ ṣe ikọlu si ninu ile rẹ.

Ninu atẹjade ti wọn fi lede, Mulala, ẹni ọgọta ọdun ni awọn aja rẹ mẹta ṣekupa lọjọ keje oṣu kinni ọdun ni dede ago mẹta ọsan.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Captain Tselanyane salaye pe iyawo oloogbe n sisẹ lọwọ ni ẹnkule ile wọn nigba to gbọ ariwo aja sugbọn o ro pe ariwo lasan ni, ko si lọ wo nnkan to ṣelẹ.

O ni Iyawo ni nitori pe agbegbe awọn jẹ agbegbe alariwo, o ni oun ro pe awọn aja naa n pariwo mọ awọn eeyan to n kọja ni.

“Nigba ti wọn tana, o ni oun lọ sinu ile lati lọ wo ọkọ rẹ sugbọn ko ri ninu ile.

“Nigba to tẹsiwaju lati wa ni o ri ọkọ rẹ ni ita gbangba to sun si lilẹ, ti ko si mi mọ, o suu re lọ sita, to si ri awọn aja naa ti wọn bu ọkọ rẹ jẹ.”

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ajọ to n risi isẹlẹ pajawiri lo wa gbe oku ọkunrin naa ninu ile wọn.

Gẹgẹ bii ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ, ẹẹya awọn aja naa ni Staffie ati Pitbull pẹlẹ aja ibilẹ kan.

Ajọ n risi ọrọ ẹranko lorilẹede South Africa ti palẹmọ awọn aja kuro nile naa.

Tani Philemon Mulala?

Philemon Mulala jẹ ogbotagiri agbabọọlu ọmọ ilẹ Zambia tẹlẹ, to jẹ ilumọka latari bii o ṣe mi awọn meji fun orilẹede naa ninu idije CECAFA lọdun 1984 nigba ti wọpn koju orilẹede Kenya.

Ẹni ọgọta ọdun ni.

O gbabọọlu fun Mufulira, Cape Town Stars ati Dynamos.