Èrò rélùwéè 32 ní agbébọn jí gbé, ọmọde méjì àti obìnrin kan gba ìdáǹdè, ọwọ́ tẹ afurasí kan

Reluwe kan ti agbebọn se iklu si

Oríṣun àwòrán, NRC

Iroyin ti n jẹ jade nipa isọri awọn tawọn agbebọn ji gbe lọ nibudokọ reluwe to wa nilu Igueben nipinlẹ Edo nirọlẹ ọjọ Satide.

Ijọba ipinlẹ Edo si ti kede pe eeyan mọkanlelgbọn ninu awọn eeyan tawọn agbebọn ọhun ji gbe lọ nibudokọ reluwe Tom Ikimi to wa nilu Igueben nipinlẹ Edo, ni wọn ko le sọ ibi ti wọn wa bayii.

Kọmisana feto ibaraẹnisọrọ ati ilanilọyẹ nipinlẹ Edo, Chris Nehikhare lo fidi eyi mulẹ lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ.

Kọmisana salaye pe lara awọn eeyan ti wọn ji gbe naa ni olori osisẹ alaabo nibudokọ reluwe naa.

Bakan naa lo ni alakoso ibudokọ oju irin naa ati akọwe to n ja tikẹẹti lati wọ reluwe fawọn ero nibudokọ ọhun wa lara awọn ero ti agbebọn ji gbe lọ.

"Awọn agbebọn tu awọn ọmọde meji silẹ amọ ti wọn ji iya awọn ọmọ naa gbe salọ"

Amọ Nehikhare wa salaye pe awọn agbebọn naa ti tu awọn ọmọde meji silẹ amọ ti wọn ji iya awọn ọmọ naa gbe salọ.

O tun laa mọlẹ pe ọkan lara awọn ero ti wọn ji gbe naa ti jajabọ kuro ni akata awọn ajinigbe ọhun.

Gẹgẹ bo se wi “Iwa ijinigbe yii lo tii buru julọ nipinlẹ lọwọlọwọ bayii.

Awọn agbebọn naa si lo gbe ọpọ ọkọ akero wa sibudokọ reluwe naa ni aago mẹrin irọlẹ ọjọ Satide, ti wọn si n yinbọn lakọ-lakọ laibikita.

Wọn ji eeyan to to mejilelọgbọn gbe lọ nigba ti ọpọlọpọ miran farapa.

“Ọkọ ayọkẹlẹ ati ọkọ ero lawọn agbebọn gbe wa lati ko ọpọ ero reluwe lọ, ọwọ tẹ afurasi kan”

Bakan naa ni wọn wa pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ lati ko awọn eeyan naa lọ sinu igbo lai w bata.”

Kọmisana feto iroyin nipinlẹ Edo naa wa fidi rẹ mulẹ pe awọn ọlọpaa pẹlu ifọwọsowọpọ awọn fijilante ati ọdẹ ibilẹ ti n gbọn inu igbo naa yẹbẹ-yẹbẹ lati se awari awọn ero ti agbebọn ji gbe lọna.

Nehikhare tun sisọ loju rẹ pe ọwọ awọn agbofinro ti tẹ afurasi kan lori isẹlẹ yii, to si ti n se iranwọ fawọn ọlọpaa ninu iwadii wọn.

Ikọlu naa ko ni se akoba fun igbokegbodo reluwe loju irin Itakpe si Warri – Ọga agba NRC

Wayi, oludari agba fun ileesẹ to n se akojọpọ ọkọ oju irin lorilẹede Naijiria, Fidet Okhiria ti fi ọwọ sọya pe ikọlu naa ko ni da isẹ awọn duro.

Lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ ni ọga agba naa fi ọwọ idaniloju yii sọya pẹlu afikun pe isẹ lilọ bibọ ọkọ reluwe loju irin Itakpe si Warri ko ni dawọ duro.

O ni awọn yoo fi aayan kun aayan awọn lati ri daju pe eto aabo to peye tubọ ri ẹsẹ mulẹ nibudokọ reluwe naa.

A ti fi awọn ọlọpaa digboluja nidi iwa ọdaran ransẹ si Edo - Adejobi

Bakan naa, alukoro fun ileesẹ ọlọpaa nilẹ wa, Olumuyiwa Adejobi naa ti kede pe aayan ti n lọ lọwọ lati sawari awọn ero tawọn agbebọn naa ji gbe l.

O wa fọwọ gbaya pe gbogbo atilẹyin to yẹ nileesẹ ọlọpaa ilẹ wa yoo fun awọn ọlọpaa nipinlẹ Edo ati ajọ reluwe lati gba idande awọn ero naa.

Adejobi ni ọwọ yoo tẹ awọn eeyan to sisẹ ibi ọhun, ti ọga agba pata fun ileesẹ ọlọpaa lorilẹede yii, Usman Baba si ti fi ikọ agbofinro digboluja ransẹ sagbegbe naa.

Awọn ọlọpaa digboluja to n gbogun ti iwa ọdaran naa lo ni wọn yoo kun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo lọwọ lati se aseyọri.

Bawo ni awọn agbebọn se ji ọpọ ero gbe lọ ni ibudokọ reluwe Igueben nipinlẹ Edo?

Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Edo lo ti kede saaju pe awọn ajinigbe ti ji ẹgbẹlẹgbẹ ero to fẹ wọ ọkọ oju irin gbe ni ibudokọ reluwe igueben nipinlẹ Edo lọ silu Warri, to wa nipinlẹ Delta.

Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo, Chidi Nwabuzor salaye pe irọlẹ ọjọ Satide ọjọ Keje osu Kinni ọdun 2023 ni isẹlẹ naa waye.

Atẹjade kan to fi sita lẹyin isẹlẹ naa salaye pe ọpọ ero reluwe naa lo fi ara gba ọgbẹ ọta ibọn nigba ti awọn ajinigbe naa, to gbe ibọn AK 47 lọwọ ya bo ibudo reluwe naa.

Ileesẹ ọlọpaa Edo fikun pe se ni awọn ajinigbe naa n yinbọn laibikita soju afẹfẹ, ki wọn to ji awọ arinrinajo naa gbe lọ sinu igbo nla kan.

“Ọpọ awọn ero ti ajinigbe gbe salọ ni ọgbẹ ọta ibọn wa lara wọn, ọga ọlọpa fun ẹkun Igueben atawọn eeyan rẹ si ti se abẹwo sibi isẹlẹ naa."