"Wọ́n nà mí nílé ẹ̀kọ́ torí mo sọ èdè abínibí mi"

Oríṣun àwòrán, Kareem Abiodun Habeebullah
Kareem Abiodun Habeebullah, tii se ẹya Yoruba ti salaye fun BBC lori bi wọn se na a nile ẹkọ girama tori pe o n sọ ede abinibi rẹ ni kilaasi.
Nigba to n salaye bi isẹlẹ naa se waye lọdun 2010, o ni se ni oun maa n ba Gẹẹsi ja lati sọ jade nigba ti oun wa nile ẹkọ girama.
O ni olukọ wa pe oun lọjọ kan lati dahun ibeere kan ni kilaasi, ti wahala si de fun oun lati salaye ara oun ni ede oyinbo.
“Mo mọ idahun ibeere ti olukọ n bi mi amọ ede abinibi mi ni mo le fi salaye idahun naa, ti yoo fi gun rege.
Se ni olukọ wa yari kanlẹ pe oyinbo ni mo gbọdọ fi sọrọ, o wa sẹgbẹ mi, to si n na mi gidigidi, to si n sọ fun mi pe n ko gbọdọ sọ ede Gẹẹsi mọ ni Kilaasi.”
Amọ kii se Kareem nikan lo jẹ iru iya bayii nile iwe nitori gbogbo akẹkọọ to ba sọ ede abinibi nile ẹkọ lorilẹede Naijiria, lo n jẹ sege iya.

Oríṣun àwòrán, Kareem Abiodun Habeebullah
Bawo ni yoo se rọrun lati fi ede abinibi kọ akẹkọọ alakọbẹrẹ tawọn obi rẹ tẹdo si agbegbe ajeji?
O se ni laanu pe lẹyin ọgọta ọdun ti Naijiria ti gba ominira lọwọ ilẹ Gẹẹsi, sibẹ, ede oyinbo si ni ede to jẹ itẹwọgba, tijọba lu ni ontẹ lati maa sọ jade nita gbangba.
Bakan naa Gẹẹsi ni ede to jẹ itẹwọgba lawọn ile ẹkọ gbogbo to fi de fasiti ati lawọn ileesẹ to jẹ tijọba ati aladani.
Amọ iroyin idunnu ni pe iyipada ti n waye lori igbesẹ yii.
Minisita feto ẹkọ, Adamu Adamu ti kede losu kọkanla ọdun 2022 pe ede abinibi ni ki wọn fi maa kọ awọn akẹkọọ alakọbẹrẹ fun ọdun mẹfa akọkọ.
Awijare rẹ lori igbesẹ naa ni pe akẹkọọ yoo tete ja fafa lati kẹkọọ yege, ti wọn ba fi ede abinibi kọ nile ẹkọ nile ẹkọ alakọbẹrẹ.
Amọ ko tii daju boya wọn yoo se amusẹ asẹ yii nitori iyapa ede to to okoolelẹgbẹta ati marun (625) ede abinibi to wa lorilẹede Naijiria.
Bakan naa, ọpọ ẹya lo n lọ kaakiri orilẹede Naijiria, ti wọn ko si joko si agbegbe abinibi wọn, eyi to le mu ko nira lati fi ede abinibi agbegbe ti wọn tẹdo si kọ awọn ọmọ wọn nibẹ.

Oríṣun àwòrán, AFP
“O dara lati fi ede abinibi kọ ọmọ amọ asọ ko ba Ọmọyẹ mọ fun Naijiria lori igbesẹ na”
Ọpọ awọn eeyan to ba BBC sọrọ lori igbesẹ fifi ede abinibi kọ awọn akẹkọọ alakọbẹrẹ lo woye pe igbesẹ naa dara amọ o ti pẹ ju ki ijọba to fontẹ lu.
Bakan naa ni awọn miran woye pe igbesẹ naa kii se eyi to le seso rere fun ẹka eto ẹkọ orilẹede yii.
Tayo Adeyemo sọ fun BBC pe “Fun ọpọlọpọ ọdun, ede Gẹẹsi la maa fi n kọ akẹkọọ nile ẹkọ, n ko si lero pe o se e yipada mọ bayii nitori pe asọ ko ba Ọmọyẹ mọ, ọmọyẹ wa ti rin ihooho wọ ọja.
















