Àwọn olóṣèlú ló wà nídìí ìfẹ̀hónúhàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 'Polytechnic Ibadan'- Fawale

Oríṣun àwòrán, others
Ile ẹkọ gbogbo niṣe Polytechnic Ibadan ti ni ki awọn oludari awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa lọ maa rọkun nile fun igba diẹ, ti wọn si tun sun idanwo saa akọkọ ti wọn fee beere lonii, ojo kẹsan oṣu kinni ọdun 2023 siwaju latari iwọde ti awon akeko naa ṣe loni.
Ninu atẹjade kan ti Ọga agba Ile ẹkọ naa, Arabinrin Modupe Fawale, fowo si, o ṣalaye pe wọn ti sun idanwo naa siwaju, ti ko si sọ ọjọ ti idanwo naa yoo beere.
Fawale nii awọn oloṣelu lọwọ ninu ifẹhonuhan naa, nitori awọn ẹgbẹ akẹkọọ ile ẹkọ kọ lati pe akiyesi awon alaṣẹ ile ẹkọ naa si edun ọkan wọn ṣaaju ifehonuhan ọhun ti wọn ṣe.
Akọwe ni ifẹhonuhan awọn akẹkọọ ile ẹkọ gbogbo niṣe Polytechnic Ibadan lo mu idiwoo baa igoke godo ọkọ, to si ṣe idiwọ fun awọn oṣiṣẹ, ara adugbo ati awọn to n lọ sinu ile ẹkọ Faṣiti Ibadan latari bí wọn ṣe tí awọn ilẹkun ile ẹkọ naa pa.
Ki lo fa ifẹhonuhan naa?
Awọn akẹkọọ ile ẹkọ giga gbogbo nisẹ Polytecnic Ibadan n fẹhonuhan lori ẹkun owo ile igbe awọn akẹkọọ ile ẹkọ ti afikun deba.
Wọn ni ẹgbẹrun marun un owo ti awọn n san tẹlẹ, ti awọn alaṣẹ ile naa si ti sọ di ẹgbẹrun lọna ẹedegbejo naira, eyi ti ko dun mọ ninu rara.
Afikun ọhun lo fa ifẹhonuhan ti awọn akẹkọọ ṣe ni owurọ oni niwaju ilẹ ẹkọ naa niluu Ibadan.
Bayii, awọn Igbimọ alaṣẹ ile ẹkọ Polytechnic Ibadan ti ro awọn obi lati baa awọn ọmọ sọrọ, ti wọn si tun ṣeleri lati kede ọjọ miran ti idanwo o bẹrẹ














