Ìkọlù tún wáyé l‘Osun, dúkìá bàjẹ́, ẹnìkan farapa, APC, PDP tahùn síra wọn

Oríṣun àwòrán, others
Awọn afurasi agbebọn kan ti ṣe ikọlu si ọọfisi ipolongo ibo to jẹ ti kọmisọna ana fun ọrọ isẹ ati irin ajo nipinlẹ Osun, Onimọ ẹrọ Remi Omowaye niluu Ilesa.
Amọ ẹgbẹ oṣelu APC ti fẹsun kan ẹgbẹ oṣelu PDP pe awọn lo wa nidi ikọlu naa
Iṣẹlẹ ọhun waye ni owurọ ọjọ Aiku, ti apa ibon si wa ni gbogbo ilẹkun abawọle ọọfisi naa.
Bakan naa, ni wọn tun ba ọpọlọpọ patako ipolongo ibo ati asia ẹgbẹ APC pẹlu awọn nkan miiran jẹ.
Awọn janduku miiran tun ṣe ikọlu si Sunkanmi Obisesan, ẹni to jẹ osisẹ agba fun olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Osun, Timothy Owoeye.
Ikọlu naa waye ni agbegbe ifofin niluu Ilesa lọsan ọjọ Aiku, ti wọn si gbe Obisesan digbadigba lọ si ile iwosan Wesley niluu Ilesa, lẹyin to farapa.

Oríṣun àwòrán, others
Igba keji ree laarin ọsẹ meji ti ikọlu yoo waye, àwọn janduku fẹ pa mi - Olori ile Asofin
Nigba to n ba awọn eeyan ati awọn akọroyin sọrọ lẹyin to ṣe abẹwo si ọfisi ẹgbẹ naa, Olori ile asofin nipinlẹ Osun, Timothy Owoeye bu ẹnu atẹlu bi ikọlu lemọlemọ ṣe n waye, ti wọn si n kọlu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Osun.
Owoeye ni ikọlu keji ree laarin ọsẹ meji, to si tun ni iṣejọba ẹgbẹ oṣelu PDP lo n fa gbogbo rogbodiyan ati ikọlu to waye si ẹgbẹ oṣelu APC
“Ọsẹ meji sẹyin, wọn gbiyanju lati pa mi. Ni ana yii, ọlọlajulọ, Adegboyega Oyetola fi ẹsẹ kan ya si Ilesa nigba to n rinrinajo lọ si niluu Akure lati kopa ninu ipolongo ibo fun oludije aarẹ fẹgbẹ APC, Bola Tinubu, ti a si pe gbogbo ẹgbẹ jọ.
“Ohun iyalẹnu lo jẹ nigba ti a de pada ni aarọ yii, ti a si ripe wọn ti fi ibọn ja gbogbo ilẹkun abawọle.
Igba keji ree laarin ọsẹ meji. Ọpọ igba a ti fi ikọlu naa to awọn agbofinro leti sugbọn wọn ko ri nnkankan ṣe si.
“A dupẹ pe ẹmi eeyan ko sọnu. A tun ti fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti laarọ yii, ati pe eyi ti fihan gbangba pe isẹ ọwọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni nitori janduku ni a mọ wọn si.
“Ori lo ko mi yọ o lọwọ awọn agbenipa nibi ọsẹ meji sẹyin.”

Oríṣun àwòrán, others
Ẹ mu ileri tẹ ṣe fawọn Janduku yin ṣẹ, a ko mọ hunkohun nipa ikọlu si yin - PDP fesi pada,

Oríṣun àwòrán, others
Ẹgbẹ oṣelu PDP ti fesi si ẹsun ti ẹgbẹ oṣelu APC fi kan an, pe oun lo wa nidi ikọlu lemọlemọ to n waye sawọn ọmọ ẹgbẹ naa nipinlẹ Osun.
PDP wa fesi pada fun APC pe ko yọ oun kuro ninu gbogbo laasigbo to waye ninu ẹgbẹ oṣelu naa.
Atẹjade kan ti alaga fidihẹ fẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Osun fi tako ẹsun ti ẹgbẹ oṣelu APC fi kan an ni esi naa ti jẹyọ.
PDP ni ki APC mu ileri to ṣe fun awọn janduku rẹ wa si imusẹ, ki awọn onitọhun le dẹkun ikọlu ti wọn n se sawọn ọmọ ẹgbẹ APC naa.
PDP wa fewe ọmọ mọ APC leti pe ko dẹkun lati maa naka si ẹgbẹ oṣelu naa lasiko tawọn janduku ba kọlu awọn ọmọ ẹgbẹ naa nitori oun kii ṣe iranṣẹ iku.
“Gbogbo awọn ikọlu wọnyi lo jẹ ohun iyalẹnu fun wa, sugbọn ohun ti agbọ ni pe bii ileeṣẹ ọlọpaa ṣe mu Asiri Eniba ati Rasheed Oko nigba eto idibo, ti gomina si kọ lati dasi awọn janduku rẹ lo fa ikọlu naa.
Nnkan ti a gbọ nipe lẹyin eto idibo, Ijọba APC kọ lati ri tawọn janduku rẹ ro lẹyin ti wọn ti wa pọ fun ọdun mẹrin.
“Nnkan ti a gbọ nipe awọn janduku naa n binu, ti wọn si fẹ ṣekupa Owowaiye ati awọn yoku to gba sisẹ.
Ki wa ni ti ẹgbẹ oṣelu PDP? Ijọba tiwa gbajumọ bii ipinlẹ Osun yoo ṣe dagbasoke, ti awọn araalu yoo si ri anfani ijọba jẹ.
“Ẹ jọwọ, ẹ ba awọn janduku yin sọrọ. A ko ni aaye fun yin rara.”















