Makinde àti Folarin kò ní iléeṣẹ́ l‘Oyo bí wọn ṣe lówó tó, olóṣèlú oní pọtimátò ni wọ́n - Adelabu
Adebayo Adelabu: 20% ni àṣeyọrí Makinde l‘Oyo fọ́dún mẹ́rin, iṣẹ́ tí kò ṣe ló pọ̀ jù
Oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu Accord, Oloye Adebayo Adelabu, ti ọpọ eeyan mọ si Penkelemesi ti sọrọ nipa eto iselu nipinlẹ Oyo.
Adelabu lasiko to n ba BBc Yoruba sọrọ tun mẹnuba bo se n da si agbega eto ọrọ aje nipinlẹ Oyo pẹlu bo se n dale isẹ silẹ ni ọdọọdun.
Amọ oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu Accord naa wa bu ẹnu atẹ lu awọn alatako rẹ nidi oselu, eyiun gomina SEyi Makinde ati Teslim Folarin.
Seyi Makinde lo tun n dije fun ipo gomina lati beere fun saa keji lori aleefa nigba ti Oloye Teslim Kolawole Folarin n dije bakan naa labẹ asia ẹgbẹ oselu APC.

Oloselu onipọtimato ni Makinde ati Folarin, igi da, ẹyẹ fo ni wọn - Adelabu
Ninu ọrọ rẹ, Adelabu ni olowo ni awn alatako oun mejeeji, ti Makinde si kede pe Biliọnu mejidinlaadọta ni oun ni lọwọ nigba to n kede dukia rẹ lasiko to gori ipo gomina.
O fikun pe saa mẹta ọtọọtọ ni Teslim Folarin fi wa nile asofin agba to n soju ipinlẹ, ti apapọ rẹ jẹ ọdun mejila to fi n gba owo Naijiria.
Amọ Penkelemesi wa n fi ika hanu pe o se ni laanu pe awọn oloselu olowo naa ko da ileesẹ kankan silẹ nipinlẹ Oyo lati gba awọn ọdọ sisẹ.
"Oke okun ni Makinde ati Folarin n kowo wọn lọ, oloselu onipọtimato ni wọn, igi da, ẹyẹ fo.
Bi nnkan ba daru pẹrẹ, wọn yoo sa kuro nipinlẹ Oyo ni, nitori wn ko ni ileesẹ kankan nibi.
Amọ ọdọọdun ni emi n da ileesẹ silẹ, ti mo si n gba awọn eeyan sẹnu isẹ.
Koda, mo tun di da ileesẹ silẹ lẹyin ti mo kuna ipo gomina, mo si ti n daleesẹ silẹ, ki n to dije fun ipo gomina.
Ibi ni awọn aya, ọmọ ati gbogbo ẹbi mi wa patapata, ibi ni mo ti dagba, ko si ibi ti mo fẹ salọ."

"Ifẹ ilu lo jẹ mi logun, owo ti mo n le ti to"
Nigba to n salaye idi to se tun fẹ pada du ipo gomina fun igba keji lẹyin to fidi rẹmi lọdun mẹrin sẹyin, Adelabu ni ifẹ ilu lo jẹ oun logun.
O salaye pe gbogbo awọn olowo to ti ku tipẹtipẹ ko si ẹni to ranti wọn mọ bikose awọn eeyan to ti sisẹ sin ilu.
"Aye si n ranti Azikwe, Balewa, Akintola Awolowo ati bẹẹ bẹẹ lọ nitori isẹ takuntakun ti wọn se fun ilu, ti ko si sẹni to ranti awọn olowo to ti ku.
Mo fẹyin ti gẹgẹ bi igbakeji gomina ni banki apapọ ilẹ wa, mo si ri pe owo ti mo ti le ti to gẹẹ, ni mo se dawọ isẹ duro, mo fẹ sisẹ sin ilu ni bayii.
Baba Penkelemesi, ọdun mẹrindinlọgọta to ti ku ree, aye ko gbagbe wọn nitori pe wn fi ara sin ilu."
"Ida ogun ninu ọgọrun ni aseyọri ti mo le fun Seyi Makinde fọdun mẹrin to fi se gomina l‘Oyo"
Nigba to n se agbeyẹwo isejọba gomina Seyi Makinde lati ọdun mẹrin sẹyin nipinlẹ Oyo, Penkelemesi ni ida ogun ninu ọgọrun pere ni odiwọn isejọba rẹ.
O ni ọpọ isẹ ni Makinde ko se , oun si ti se agbeyẹwo isejọba rẹ denudenu lai fi iyapa tabi orogun oselu se.
"Mo se igbelewọn isejọba Seyi Makinde lori koko ohun meje, eyiun eto ọgbin, eto ẹkọ, ọna sise ati igbokegbode ọkọ, eto ayika, eto aabo, idalesẹsilẹ, eto ilera ati ile olowo pọọku ati ipese isẹ oojọ.
lọrun ri inu mi, ko se nkankan lawọn ẹka yii, n ko fi ti oselu se.
Tẹgbọn taburo ni emi, Makinde ati Folarin, ẹgbọn ni awn mejeeji jẹ si mi, ọmọ Ibadan si ni awa mẹtẹẹta.
Amọ ta ba yọwọ ti oselu kuro, o yẹ ka le sọ otitọ ọ̀rọ fun ara wa nitori ọdun 2015






