Kìí ṣe wí pé Ooni fẹ́ràn láti kó ìyàwó jọ, ìdí tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi ríbẹ̀ rèé- Ẹ̀gbọ́n Ọọni

Ẹgbọn Ooni ti ilu ile ife, Ọmọọbabirin Folashade Ogunwusi Fadairo ni Ọọni ko fi gba kankan fẹran lati ni iyawo pupọ rara sugbọn nitori awọn nnkan to sẹlẹ si lo fa to fi gbe igbesẹ naa.
Ọmọọbabirin Folashade tu kẹkẹ ọrọ ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹlẹ kan niluu Eko. O ni nigba ti awọn ni ọmọde ile ijọsin Deeper Life ni awọn lọ, ti wọn ko si fi aye silẹ fun ọkunrin lati ni iyawo meji tabi ju bẹlọ.
O tẹsiwaju pe ọpọ igba ni Ooni ti sọ pe oun ko nifẹ si ile olorogun sugbọn o jẹ nnkan to ni lati ṣe gẹgẹ bii Ọba alade to jẹ.
“Ti a ba ranti, nigba to n ṣe ayẹyẹ iranti ọjọ igbeyawo rẹ, Ọọni sọ awọn ẹdun ọkan rẹ kan. Ko nifẹ si ile olorogun sugbọn gẹgẹ bii Ọba alade, o jẹ ohun to ni lati ṣe .
“Ni ilẹ Yoruba, ile olorogun ko jẹ tuntun rara ati pe inu rẹ ni wọn bi wa si. Fun apẹẹrẹ, Baba to bi baba wa fẹ Iyawo mẹjọ.
"Ni idile iya, Baba to bi iya mi fẹ iyawo mẹjọ tabi meje ni wọn fẹ. Fifẹ iyawo pupọ jẹ nnkan to ni lati ṣe gẹgẹ aṣoju ilẹ Yoruba.
“Sugbọn mo ro pe nnkan to yẹ ko yẹra fun.”
Ooni ni lati fẹ ju iyawo ẹyọkan lọ

Oríṣun àwòrán, others
Ọmọọba tẹsiwaju pe Olodumare lo yan Ọọni lati ṣe ohun to yẹ ko ṣe gẹgẹ bii Oba ti ko si nnkan to le daduro.
O ni gẹgẹ bii Ọba alade o ni lati fẹ ju iyawo ẹyokan lọ.
“Bawo ni mo ṣe fẹ sọ fun yin? Nnkan ti Olodumare fẹ ko ṣe ni ni nnkan to n ṣe. Nnkan ti wọn yan fun ni.
“Yoruba ni ibi ori ba dani si ni a n gbe, ibi ti ori da si, ibẹ loun gbe yẹn.”















