Obasanjo sọrọ sókè lórí pé ó fẹ́ ṣe sáà kẹta nípò ààrẹ

obasanjo

Oríṣun àwòrán, Others

Aarẹ tẹleri nilẹ Naijiria, Oloye Olusegun Obasanjo ti sọ asọyan ọrọ lori pe o fẹ se saa kẹta nigba to wa nipo aarẹ.

Ẹsun yii ni wọn ti fi kan Olusegun Obasanjo lọpọ igba eyi to mu kawọn eeyan maa foju abuku wo aarẹ tẹlẹ naa.

Amọ nigba to n sọrọ lori ẹsun naa, aarẹ tẹlẹ ri naa ni oun ko figba kankan fẹ dije dupo aarẹ fun igba kẹta.

O ni bi oun ba fẹ dije gẹgẹ bi aarẹ fun igba kẹta, ko ni na oun ni nkankan nitori oun mọ awọn ọna ti oun maa gba lati di aarẹ lẹẹkẹta.

"Naijiria nilo oludari to ni itara, ọgbọn, oye ati abuda lati yii nkan pada si rere"

Obasanjo sisọ loju ọrọ yii ni Ojobo, ni bi apero fun awọn adari ilẹ Afrika.

O ni, Naijiria gbọdọ yan adari to mọ oun ti yoo ṣe, ti orilẹede yii yoo fi goke agba, ko si ni jẹ adari tiyoo ṣeleri lai musẹ.

Bakan naa, Olusegun Obasanjo tun se alaye awọn nkan pataki ti aarẹ to n bọ gbọdọ tete koju nigba ti o ba bẹrẹ iṣẹ lẹyin eto idibo ọdun yii.

O wa ṣe akiyesi pe awọn isoro bi ipenija lẹka aabo, ninu eyiti iwa ijinigbe, ipaniyan awọn agbebọn ati awọn iwa miran ni aarẹ titun gbọdọ mojuto.

O ni orilẹ-ede yii wa ni “akoko to ṣe pataki” ati pe o nilo oludari ti o ni itara, ọgbọn,oye ati abuda lati yii nkan pada si rere.

" Ẹni ti yoo jẹ aarẹ to n bọ gbọdọ loye eto ọrọ aje, ko mọ nipa owo iranwọ ori epo rọbi ati yiyanju ajẹẹlẹ gbese"

Obasanjo tẹsiwaju pe “O wu mi ki ọkunrin ti yoo jẹ aarẹ ti n bọ, jẹ aṣaaju ti yoo loye eto-ọrọ aje.

O tun gbọdọ mọ nipa owo iranwọ ori epo rọ̀bi, bakan naa lo si tun gbọdọ mọ nipa bi yoo ṣe yanju ajẹẹlẹ gbese orilẹ-ede yii.

Obasanjo ninu ọrọ rẹ sọ pe awọn ọdọ orilẹ-ede Naijiria gbọdọ ni imọ kikun lori oṣelu nitori ọpọ igba ni ẹsin ati ẹya awọn oludije maa n dena yiyan adari gidi lorilẹede yii.

"Emi kọ́ ní mo kọ lẹ́tà sì ìjọba ilẹ̀ Gẹẹsi lati mase da si idibo Naijiria"

Ninu iroyin miiran, Olusegun Obasanjo ti tako iroyin kan to wa nita pe o kọ iwe si awọn alaṣẹ ilẹ Gẹẹsi lati mase da si eto oṣelu orilẹ-ede yii.

Ninu iroyin ofege to gbode, o ni Obasanjo fẹsun kan awọn alaṣẹ ilẹ Gẹẹsi wí pe wọn gbiyanju lati yọ o unloye nigba to jẹ aarẹ Naijiria.

Iroyin naa ni aarẹ tẹlẹ naa ni ijọba ilẹ Gẹẹsi lo gbe Fulani wọle gẹgẹ aarẹ nitori naa ni orilẹ-ede Naijiria ṣe n ri awọn idojukọ.

Nigba to n fesi si iroyin ofege naa, Kehinde Akinyemi tii se amugbalẹgbẹ Obasanjo ni irọ lasan ni iroyin naa.

Lẹyin iwe ti Olusegun Obasanjo kọ si awọn ọdọ orilẹ-ede yii ni ọjọ kini ọdun yii ati eyi to fi ki Ọjọgbọn Toyin Falola lọjọ ibi rẹ, Ọbasanjọ ko ti kọ lẹta miran.

O ni awọn akọroyin gbọdọ ṣe iwadii finnfinni, ki wọn to gbe iroyin sita papa julọ iroyin ti Oloye Ọbasanjọ ko ba fi ọwọ sii.