Èèyàn 5 kú, 13 farapa nígbà tí ọkọ̀ ya wọ ààrin èrò tó fẹ́ sọdá títì

Aworan

Oríṣun àwòrán, WEIBO

Ileeṣẹ ọlọpaa ti kede pe awakọ kan ti ya wọ aarin ero, to si ṣekupa eeyan marun un, ti awọn mẹtala mii si farapa yanayana.

Isẹlẹ naa lo ti fa ọpọlọpọ awuyewuye lorilẹede China, ti ọpọ si ni awakọ ọhun mọọmọ ya wọ aarin ero ni.

Awọn fọnran to wa lori ayelujara safihan bi awakọ naa ṣe jade kuro ninu ọkọ, to si fọn owo ṣoke lẹyin to kọlu awọn ero naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọkunrin ọhun, ẹni ọdun mejilelogun ti wa ni ahamọ, ti iwadi si ti bẹrẹ lori isẹlẹ naa.

Isẹlẹ naa waye lasiko tawọn ero n duro de ina to n dari ọkọ loju popo lati sọda - Osojumikoro

Isẹlẹ naa waye lọjọru ni ibudo igbọkọsi lapa guusu orilẹede China.

Osojumikoro kan salaye pe “ọkunrin naa mọọmọ ya wọ arin ero nigba ti wọn duro de ina to n dari ọkọ loju popo lati sọda.

O gun wọn mọlẹ pẹlu ọkọ rẹ, lẹyin eyi, o tun wọ rifaasi, to si tun ṣe awọn eeyan lese.

“Ko ki n ṣe pe awakọ naa n sare rara sugbọn awọn ero ko tete fura nitori wọn ko ro pe o ya wọ arin wọn lati ṣe wọn lese ni.”

Bakan an ni awakọ ọhun tun kọlu ọlọpaa pẹlu kẹkẹ rẹ sugbọnh ohunkohun ko ṣe ọlọpaa naa.

Ọpọ lo ti faraya lori isẹlẹ naa, ti wọn si n fi ibanujẹ han nitori isẹlẹ naa waye nigba to ku ọjọ diẹ ti wọn yoo ṣe ayẹyẹ ọdun tuntun lorilẹede China.