EFCC ṣàlàyé ìdí tí ọwọ́ fi kọ́kọ́ tẹ Doyin Okupe ní pápákọ̀ òfurufú àti bí wón ṣe padà tú u sílẹ̀

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ atawọn iwa aitọ miran lorilẹede Naijiria, EFCC ti kede pe awọn ti tu silẹ alaga iponlogo ibo tẹlẹ fun ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Doyin Okupe silẹ lẹyin ti wọn dena irin ajo rẹ lowurọ ọjọbọ ni papa ofurufu Muritala Mohammed nipinlẹ Eko.

Agbẹnusọ EFCC, Wilson Uwujaren ni ajọ DSS lo kesi awọn pe ti gbe igbesẹ naa.

O tẹsiwajupe ajọ DSS gbe igbesẹ ọhun lori ẹsun kan to wa nilẹ tẹlẹ fun Okupe lati ọdun 2016,

O ni eyi waye nibi ọdun mẹfa ṣeyin ki ẹsun siṣe owo mọkunmọkun to waye

Okupe lori ayelujara rẹ ni papa ofurufu Muritala Mohammad ni awọn EFCC ọhun ti de na rẹ lati maa le lọ si oke okun lati lọ gba itọju.

Ẹwẹ, O ni pe wọn ti tu oun silẹ, ti wọn si tọrọ aforigin lọwọ oun lori igbesẹ wọn.

"Awọn EFCC dena de mi ni papa ofurufu nigba ti o n lọ orilẹede UK fun itọju, ti mo si ba wọn ọfisi wọn.

"Lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti wọn ti wọn ti gba paali iwe irina mi .

"Mo ti kuro niọfisi ajọ naa bayi nipinlẹ Eko, ti ajọ EFCC si ti tọrọ aforigin lọwọ mi."

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ki ni o ṣelẹ laarin Okupe ati ajọ EFCC?

Aipẹ yii ni Ile ẹjọ kan ni ilu Abuja ti sọ pe oludari agba ikọ ipolongo fun Peter Obi ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Ọmọwe Doyin Okupe jẹbi ẹsun gbigba iye owo igba miliọnu naira lọwọ olugbaninimọran agba ijọba lori eto abo, Col. Sambo Dasuki ti wọn si ti ran an lọ si ẹwọn ọdun meji.

Bakan naa ni ile ẹjọ tun paṣẹ pe ko ṣe ẹwọn ọdun meji lori ẹsun to ni ṣe pẹlu abala ikarunlelọgbọn titi de ikọkandinlọgọrin tabi ko san faani ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta.

Anfani lati san faani mejeeji naa ni wọn fun un pe o lee san an tẹle ara wọn. Ẹwẹ, ni ti iye ọdun ti wọn ran an lọ ẹwọn, wọn fun un ni anfani pe o lee ṣe mejeeji papọ.