Afurasí ìyálé dáná sun ìyàwó àbúrò ọkọ̀ rẹ̀ mọ́lé

aworan

Oríṣun àwòrán, Uchechukwu nwaokoro/facebook

Ọpọlọpọ asiri lọ tu si gbangba nipa iku obinrin kan ẹni ti iyale rẹ pa ni Owerri nipinle Imo.

Iku arabinrin Uchechukwu Faith Nwaokoro ni ya ọpọlọpọ lẹnu. Ninu ifọrọwerọ pẹlu akọroyin BBC,ọkọ arabinrin naa,

Emmanuel Nwaokoro ati aburo ologbe Ifuruna Nwanneka ni awọn ko mọ nkan to fa iṣẹlẹ buruku naa.

Uchechukwu lọ jade laye lẹyin igba ti iyale rẹ didi fi ina si lara

Nigba ti o n ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ti waye, Emmanuel ni iyawo ẹgbọn oun lọ wọle lati ko awọn dukia rẹ lẹyin igba ti oun ati ọkọ rẹ to jẹ ẹgbọn Emmanuel ti pinya.

Emmanuel ni nitori wi pe ile ti su ni awọn ṣe jẹ ki afurasi naa sun inu ile pẹlu awọn moju.

O ni laarin oru ni iyawo oun Faith kẹfin ina to n jo ninu iyara igbalejo ti oun si sara fi omi paa.

Ṣugbọn bi oun ti jade ni iyawo oun Faith figbeta pe ẹnikan da nkan si oun lara, ko pe sigba yẹn ni ina sọ lara rẹ.

Emmanuel ni gbogbo ilakaka oun lati pa ina ara iyawo oun lọ ja si pabo kí ina naa to gba emi rẹ. O ni ile iwosan mẹta ni oun gbe iyawo oun Faith lọ ti awọn meji kọ lati fun ni itọju ko to gbemi mi.

O ni afurasi naa ni awọn ko ti ri titi di akọkọ yii.

Gbogbo ilakaka lati ba alukoro ọlọpa sọrọ lori iṣẹlẹ naa ni o jasi pabo, ṣugbọn ọlọpa to wadii iṣẹlẹ naa lati ile iṣe ọlọpa Umuago ni iwadii si tẹsiwaju .