Irọ́ ni pé nítorí búrẹ́dì ni mo ṣe lu ìyàwó mi pa,àríyànjiyàn lásán làní- Afurasi

Oríṣun àwòrán, Wilsonuwa/facebook
Ọkuunrin ti wọn fi ẹsun kan pe o pa iyawo rẹ latari ariyanjiyan lori burẹdi ti ni oun ko jẹbi ẹsun naa.
Ndubuisi Uwadiegwu sọ fun ile iṣe BBC wi pe lotito ni oun ati iyawo oun ja ṣugbọn kí i ṣe burẹdi lọ fa ariyanjiyan to yorisi iku iyawo rẹ.
Laipe ni iroyin kan lede lori ẹrọ ayelujara pe Ndubuisi ṣeku pa iyawo rẹ nitori buredi.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu Chukwuebuka ibatan ologbe naa ṣalaye pe ariyanjiyan bere nigba ti Ogochukwu iyawo re bere owo burẹdi lọwọ ọkọ rẹ,
O ni iyawo Ndubuisi fẹ lo owo naa lati burẹdi fun ọmọ wọn, kí ọkọ re to jẹ burẹdi to ra lai gbaṣe .
Eyi lọ fa ariyanjiyan ti ọkọ fi fo digi mo iyawo rẹ ti o si naa ọmọ rẹ ọmọ ọdun mẹrin-lelogun nitori oun gbe lẹyin iya rẹ.
Chukwuebuka ni ọjọ Kẹsan oṣu kejila, ọdun to kọja ni Ogochukwu pe oun to ṣi ṣalaye bí ọkọ rẹ Ndubuisi ṣe lu ti o si ni ifarapa.

Kini Dokita so?
Lẹyin ayẹwo ni ile iwosan awọn dokita ni ọkan lara awọn iṣan ara rẹ ni o ti ja ti wọn si daari wọn si ile iwosan UNTH Enugu nibiti o ti dagbere faye.
Ninu ọrọ rẹ Chukwuebuka ni iwadii fi han pe opo igba ni Ndubuisi maa n na iyawo rẹ ti awọn ara adugbo wọn naa jẹri si.
Ṣugbọn iwadii awọn agbofinro fi han pe aisan ẹjẹ ruru(Hypertension ) lọ fa iku ogochukwu.
Ninu awijare rẹ Ndubuisi ni oun kò jẹbi ẹsun iseku pani nitori wi pe òun ko momoo naa iyawo oun
ljọ naa.O ni koda oun wa ni abule nigbati wo pe oun pe ara iyawo oun le eleyi to jẹ ki oun gbelo di ile iwosan ko to jade laye.














