Mó kìlọ̀ fún ìyá mí pé kò má pariwo lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha àmọ́ kò gbọ - Pricilia, ọmọ Iyabo Ojo

Aworan

Ọmọ gbajugbaja osere tiata, Iyabo Ojo, eyiun Pricilia Ojo, ti salaye bo ṣe gbiyanju lati da iya rẹ lẹkun pe ko ma lọ sori ayelujara lori ọrọ Baba Ijesha lọdun 2021.

Pricilia tu kẹkẹ ọrọ yii silẹ nigba to n kopa ninu ifọrọwerọ lori ayelujara pẹlu Stephanic Coker.

Ọmọbinrin naa ni o dun oun pupọ bii iya oun ṣe ba awọn eeyan kan ja lori ayelujara sugbọn oun gbagbọ pe iya oun n ja fun ẹtọ ọmọniyan ni.

‘”Ti iya mi ba ba eeyan ja, o ma n pariwo, o ti mọ mi lara sugbọn mo sọ fun Iya mi pe ko maa jẹ ki awọn eeyan ri si lori isẹlẹ naa.

“Ti iya mi ba n binu, ẹ ma ro pe o ko rira eeyan sugbọn bo ṣe ma ṣe ifẹhonuhan tiẹ niyẹn"

“Ti iya mi ba n binu, ẹ ma ro pe o ko rira eeyan sugbọn bii o ṣe ma ṣe ifẹhonuhan tiẹ niyẹn."

“Gbogbo wa la mọ nigba ti ọrọ Baba Ijesha sẹlẹ, mo ba iya mi sọrọ pe ko maa lọ sori ayelujara rara, o dẹ ni oun ti gbọ si mi lẹnu

“Sugbọn nigba ti mo kuro ninu yara iya mi, o ti ilẹkun, mo pariwo sugbọn iya mi fariga, mo pe ẹrọ ibanisọrọ rẹ sugbọn ko da mi lohun rara.

“Mo ṣe eleyi nitori n ko nifẹ si gbogbo wahala ori ayelujara sugbọn mo ni igbagbọ pe iya mi n ja fun ẹtọ ọmọ niyan ni”

Ki ni o ṣelẹ laarin Baba Ijesha ati Iyabo Ojo?

Gbajumọ osere tiata lobinrin ọhun, Iyabo Ojo, lo gbara ta lori ọrọ akẹẹgbẹ rẹ lagbo tiata, Olanrewaju Omiyinka , ti ọpọ eeyan mọ si Baba Ijesha.

Baba Ijesha ni wọn fẹsun kan pe o se asemase pẹlu ọmdebinrin, ọmọ ọdun mẹrinla, to jẹ ọmọ adẹrinposonu ori ayelujara, Princess Comedian.

Iyabo leri leka ninu awọn fidio to se loju opo Instagram rẹ, to si ṣe ileri pe oun yoo ba ọrọ ẹsun ti wọn fi kan Baba Ijesha de opin, ti idajọ ododo yoo si waye.

Ẹsun naa gba ọna miran yọ lẹyin ti Iyabo Ojo gbe fidio kan jade ninu eyi ti Baba Ijesha wa.

Ninu fọnran aworan naa ni Baba Ijesha ti joko silẹ, to si n bẹbẹ pe ki wọn dari jin oun.

Fidio naa ti Iyabo Ojo gbe soju opo Instagram rẹ lo se afihan Baba Ijesha to n sọ pe ki wọn dari jin oun nitori isẹ esu ni.

Ọpọ awọn osere tiata ni Iyabo Ojo gbena woju wọn lori ọrọ naa.

Ile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko si ti ran Baba Ijesha lọ si ẹwọn lẹyin ti wọn kede pe o jẹbí ẹsun sise asemase pẹlu ọmọ ọdun mẹrinla naa.