Ìjọba ṣetán láti gbà àwọn dókítà láti ilẹ̀ òkèèrè láti tọ́jú àwọn eèyàn Nàìjíríà-Osagie

aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Minisita fun eto ilera lorilẹede Naijiria, Ọmọwe Osagie Ehanire, sọ pe ijọba apapọ ni eto lati da awọn dokita ati nọọsi ti wọn jẹ ọmọ bibi orilẹede yii ti wọn n ṣiṣẹ ni okeere pada, ati lati jẹ ki wọn pada si iṣẹ ni awọn ile-ẹkọ giga ati awọn ile iwosan lorilẹede yii.

 Nigba to n soro nibi akanṣe eto lori awon aseyori ijọba aarẹ Muhammadu Buhari papa julọ eka Isegun nilu Abuja, olu-ilu orilẹ-ede yii, minisita naa sọ pe oun loye bi awọn dokita se n kuro lorileede yii.

Minisita naa sọ pe ọpọ awọn dokita ati nọosi ni wọn ṣan owo to ye fun bo ṣe yẹ.

Ọgbẹni Ehanire sọ pe ijọba apapọ n gbiyanju lati yanju iṣoro naa nipa ipese agbegbe to bojumu fun awọn dokita

 O fi kun un pe iṣoro aito awọn dokita jẹ iṣoro ti o kan gbogbo agbaye, kii ṣe Naijiria nikan.