MC Oluomo fún Seun Egbegbe ní ipò olórí gárèèjì ni Eko

Musiliu Akinsanya ẹniti gbogbo aye mo si MC Olú Oluomo ti sọ oṣere tiata Segun egbegbe ẹniti o ṣẹṣẹ ri itusilẹ ni ọgba ẹwọn lẹyin bii ọdun marun ṣe olori igun kan ninu awọn papakọ keke maruwa ni ipinle Eko.
Ninu atẹjade kan ti Mc oluomo filede lori ẹrọ ayelujara instagram rẹ.
Seun ẹni ti lọ si ọgba ẹwọn fun ẹsun ole jija ni ọpọlọpọ awọn ọrẹ rẹ ti ko silẹ lataari ẹsun ti wọn ti fi kan naa.
Botile jẹ wi pe Mc oluomo ati Seun Egbegbe ti jọ ni aawọ ṣaaju ko to lọ si atimọle.
Atẹjade naa ni Mc Oluomo yonda igun awọn keke maruwa fun Seun Egbegbe lati jẹ olori wọn.
O ni ki ṣe idunu oun lati ri Seun Egbegbe pada sinu awọn iwa rẹ atijọ nitori naa ni o ṣe fun ni iṣe lati le rowo jẹun ati lati ṣe itọju obi rẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Oṣere fiimu Yoruba yii, Olajide Kareem ti ọpọlọpọ n pe ni Seun Egbegbe gba itusilẹ bayii amọ o jiya ẹṣẹ rẹ fun odindi ọdun mẹfa ati oṣu mẹjọ ninu ẹwọn.
Ninu oṣu Keji ọdun 2017 lo wọ gbaga ofin lẹyin ti wọn fi ẹsun kan-an pe o fi ọna ẹburu gba owo lọwọ awọn eniyan ti ko din ni ogoji eeyan to n ṣẹ owo ilẹ okere ni ipinlẹ Eko.
Bakan naa ni iroyin gba igboro kan nigba naa, pe o ji foonu iPhone.














