Èèyàn mẹ́tàlá ló ṣì kù ní àtìmọ́lé àwọn ajínigbé-Obaseki

Oríṣun àwòrán, GovernorGodwin Obaseki/facebook
Kini o kọkọ ṣelẹ?
Ijọba ipinlẹ Edo ni ọjọru sọ pe eniyan ogun nikan ni wọn jigbe ni ibudo ọkọ oju-irin ni ọjọ ẹti to kọja kii ṣe mejilelọgbọn.
O ni pẹlu awọn meje ti awọn eso alaabo dola ẹmi wọn lọwọ awọn ajinigbe awọn mẹtala lọ seku lọdọ awọn ajinigbe naa.
Kọmisonna ipinle Edo fun ọrọ Ibaraẹnisọrọ, Chris Nekhihare, lo fi ọrọ naa lede
O sọ pe, “iwadii fihan pe , awọn ajinigbe naa mu awọn eeyan ogun ki ṣe eniyan mejilelọgbọn gẹgẹ bi akọsilẹ ti sọ ṣaaju.
Chris ni igbakeji gomina Philip Shuaibu ti ṣe ipade pẹlu awọn olori ilu naa,awọn oṣiṣẹ alaabo lati rii daaju pe aabo to peye wa ni agbegbe naa.
Awọn to kowo rin pẹlu igbakeji Gomina ni Senato ti o n soju arin gbungbun Edo Clifford Ordia ati olori ile Igbimọ asofin Ipinlẹ Edo Marcus Onobun.
O rọ awọn ara ilu lati pese alaye ti o wulo ti yoo ṣe iranlọwọ fun awọn eso alaabo lati fi pampe ofin mú awọn to waa lẹyin iṣẹlẹ ijinigbe naa.
Komisonna ni, igbakeji Gomina Shaibu ṣalaye ipa ti ijọba n ṣe lati fopin si iwa ijinigbe o ro awọn ọba to wa ni agbegbe naa lati tẹlẹ aṣẹ ati ilana ijọba lori eto aabo.














