Lẹ́yìn ọdún kan àti oṣù mẹ́fà lákàtà agbébọn, àwọn Òbí omo 11 kégbàjarè!

Awọn obi ọmọ mọkanla ti ile ẹkọ ijọba to wa ni ilu Yauri nipinlẹ Kebbi, to ti wa ni igbekun awọn agbebon lati ọdun 2021 ti figbeta lẹyin ti wọn ko gburo awọn ọmọ wọn to wa ni igbeku naa mọ.
Wọn salaye pe niṣe ni awọn agbebon kọ lati baa awọn sọrọ nitori wọn kuna lati san owo itusilẹ fun awọn ọmọ wọn.
Lọjọbọ ọjọ kẹtadinlogun ọdun 2021 ni awọn afurasi agbebon ji o le ni ọgọrun ọmọ ile ẹkọ Federal Government College Birnin Yauri gbe ti wọn si tu awọn akẹkọọ ọgbọn ati olukọ kan silẹ ni ninu oṣu kẹwaa ọdun 2021.
Ọkan ninu awọn obi awọn ọmọbinrin to ṣi wa ni igbekun awọn agbebon ni awọn agbebọn kọ jale lati jẹ ki awọn baa awọn ọmọ naa sọrọ, ayafi ti awọn ba ṣan owo itusilẹ, eyi to to ọpọlọpọ millionu naira.
Awọn agbebọn ni awọn yoo ṣekupa awọn ọmọ naati awọn obi ba kọ lati san owo

Olori awọn obi ti awọn ọmọ wọn wa ni akata awọn agbebon Salim Kaoje ni tẹleri awọn obi ati awọn agbebon ti ni ajọsọ ọrọ lori bii awọn yoo se gba itusilẹ awọn ọmọ wọn, sugbọn lọwọ yii ajọsọ ọrọ naa ti fori san pọn.
O ni laipẹ yii awọn agbebon naa pe oun ti wọn si ṣeleri lati paa awọn ọmọbinrin mọkanla to wa ni akata wọn ti awọn obi ba kọ lati ṣan owo itusilẹ awọn ọmọ wọn.
Niyanthara Daniel, ọkan lara awọn obi awọn ọmọ naa ni oun setan lati ta ile ti awọn n gbẹ lati ṣan owo itusilẹ ọmọ oun.
O ni awọn ti duro de ijọba lati ran awọn lọwọ sugbọn niṣe ni ijọba kọ eti ikun si ẹbẹ awọn obi.
Niyanthara ni lati igbati iṣẹlẹ naa ti waye ni ọdun 2021 Gomina Ipinlẹ naa ko ti ba awọn obi tọrọ kan ṣe ipade poo tabi sọ ibiti isẹ itusilẹ awọn ọmọ awọn de.
O ni iranlowo awọn mọlẹbi ati awọn ara agbegbe awọn ni awọn gbokanle nitori wi pe gbogbo dukia awọn ni awọn ti taa lati ri wi pe awọn ọmọ naa gba itusilẹ lọwọ awọn agbebon.














