Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, àwọn olufẹ̀hònúhàn 'End Sars' mẹ́sàn-án gbà òmìnia lọ́gbà ẹ̀wọ̀n nílùú Ibadan

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Awọn ọkunrin mẹsan an ti ọwọ tẹ nigba iwọde EndSar niluu Ibadan, ti wọn si wa ni atimọlẹ lati ọdun 2020 gba ominira kuro lọgba Agodi lọjọ isẹgun ọsẹ yii

Orukọ awọn mẹsan an ọhun ni Adeshina Muyiwa, Ikechuckwu Eze, Ariyo Sodiq, Ikenna Amaechi, Oyewole Olumide, Ariyo Afeez, Taoreed Abiodun, Adekunle Moruf, ati Rasheed Tiamiyu,

Ẹsun ti wọn fi kan awọn ọkunrin mẹsan an naa ni pe wọn lọwọ ninu iṣekupa awọn ọlọpaa, dana sun ileeṣẹ ọlọpaa ati awọn ẹsun miiran lasiko iwọde End Sars lọdun 2020.

Ikede yii waye lẹyin ti Adajọ agba nipinlẹ Oyo pasẹ itusilẹ awọn ẹlẹwọn mejidinlọgọta to ti lo kọja asiko wọn lọgba ẹwọn.

Nigba to fi idi isẹlẹ naa mulẹ, Solomon Emiola, ẹni to jẹ afafẹtọ awọn ọlufẹhonuhan ọhun ni kete ti oun sin awọn olufẹhonuhan de ile wọn ni oun gbe ipe wa.

Emilola ni awọn olufẹhonuhan ọhun ti wa lakata awọn ọbi sugbọn wọn nilo iranlọwọ ati itọju to peye.

Ki lo fa iwọde EndSARS?

Ti a ko ba gba gbe, Isẹlẹ manigbagbe, ti yoo wa ni iranti awọn ọmọ orilẹede Naijiria, ni iwọde EndSARS jẹ, paapaa lẹkun guusu orilẹede yii.

Iwọde naa, to waye losu kẹwa ọdun 2020 ni awọn ọdọ fi n tako iwa ifijajẹni ti ikọ ọlọpaa to n gbogun ti iwa idigunjale (SARS) n hu si wọn laarin ilu.

 Awọn ọdọ naa si lo tu jade lọpọ yanturu fun bi ogunjọ lati fi ẹhonu han tako iwa ibajẹ awọn ọlọpaa SARS naa, ti wọn si n beere pe ki ijọba tu wọn ka.

 Idi ree ti wọn fi pe akori iwọde naa ni EndSARS.

 Gbogbo awọn olu ilu awọn ipinlẹ to wa ni guusu Naijiria atawọn ilu nla nla miran ni awọn ọdọ naa kora jọ si lati fi ẹhonu han.