OPC kò lọ́wọ́ nínú rògbòdìyàn tó wáyé ní Ọjọta - Gani Adams

Oríṣun àwòrán, others
Aarẹ Ọnakakanfo Ilẹ Yoruba, Gani Adams, ti bu ẹnu atẹlu iroyin kan to n ja kiri pe awọn ọmọ ẹgbẹ Odua People’s Congress lọwọ si rogbodiyan to waye ni agbegbe Ọjọta, loni ọjo Aje nipinlẹ Eko.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Kehinde Aderemisi fi lede, o ni ohun iyalẹnu ni rogbodiyan to waye ni agbegbe Ojota jẹ fun ẹgbẹ awọn, ti ko si si ọmọ wọn kankan nibẹ rara tabi to ṣe ikọlu si ẹnikẹni.
O ni: “ Ẹ jẹ kan yannana rẹ, isẹlẹ to waye ni Ojota larọ yii, ti iroyin kan si n gbe kiri pe awọn ọmọ ẹgbẹ OPC lo wa nidii isẹlẹ lo jẹ ohun iyalẹnu, mo si fẹ ka mọ pe ko si ọmọ ẹgbẹ kankan nibẹ lowurọ oni.
OPC ko tako idisilẹ Yoruba Nation
Aarẹ Gani Adams tẹsiwaju pe ẹgbẹ OPC ko tako idasilẹ Yoruba Nation sugbọn o gbọdọ jẹ ija gbogbo ọmọ Yoruba ni apapọ.
“A ko si lara awọn to ṣe iwọde lonii rara. A si duro loei nnkan ti a ti n sọ pe anilo lati ṣe atunṣe si eto iṣejọba orilẹede yii, ti ẹkun kọkan yoo ni anfani lati tukọ ijọba rẹ.
“O ṣe ni laanu pe awọn kan gbe iroyin kiri lati ba orukọ ẹgbẹ wa jẹ ni. Bawo ni awọn kan yoo ṣe sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ OPC lo ṣe ikọlu si awọn ọmọ adijagbara Yoruba Nation.
“Iroyin ati fọran ti a ri lori ayelujara fihan pe iwọde alaafia lo waye ni Ojota sugbọn to ba ba ibo miran jade, to si mu ẹmi yan kan lọ pẹlu.”











