Atiku bá ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣe ìpàdé lórí ìpèsè ìrànlọ́wọ́ ètò aàbò ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar/Facebook
Olùdíje ipò ààrẹ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Atiku Abubakar bá àwọn aṣojúṣofin ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣe ìpàdé lórí bí nǹkan yóò ṣe rí bí ó bá di ààrẹ Nàìjíríà .
Nínú àwọn ọ̀rọ̀ kan tó fi léde lórí ìkànní Twitter rẹ̀, Atiku sọ pé: "
Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìpàdé tán pẹ̀lú Andrew Mitchell – mínísítà fún ìdàgbàsókè àti Afrika ní iléeṣé ilẹ̀ òkèèrè, àjọ commonwealth àti iléeṣẹ́ ìdàgbàsókè nínú àwọn èèkàn ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
"Mo lo àkókò ọ̀hún láti sọ ètò tí mo ní fún Nàìjíríà nípa ààbò, ọ̀rọ̀ ajé àti ètò ẹ̀kọ́ fún wọn.
"Mo tọrọ àtìlẹ́yìn wọn, bí ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣe fẹ́ ran Nàìjíríà lọ́wọ́ jẹ́ ohun ìwúrí fún mi.”
Dino Melaye tó jẹ́ agbẹnusọ ìpolongo ìbò ààrẹ PDP ní Atiku ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn olórí iléeṣẹ́ ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lóríi ọrọ̀ ajé, ètò ààbò àti ọ̀rọ̀ ìwọlé wọ̀de.











